Desmond Elliot, Mojisola Alli-Macaulay fa ayélujára ya torí ọ̀rọ̀ wọn níle aṣòfin Eko

Awn aṣofin ipinlẹ Eko, Desmond ati Mojisolae

Oríṣun àwòrán, Desmond Elliot, Mojisola Macaulay

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Arabinrin Mojisola Alli-Macaulay to jẹ akẹgbẹ aṣofin nipinlẹ Eko sọ wi pe ko si igba ti awọn ọdọ lorilẹede Naijiria kii fa igbo nitori naa ni ori wọn ṣe n gbona ni igba gbogbo

Iroyin ni ibi ijoko Ile Aṣofin nipinlẹ Eko ni Alli-Macaulay ti sọ ọrọ naa lẹyin rogbodiyan to waye lasiko ifẹhọnuhan EndSars, ti awọn onijagidijagan gba mọ wọn lọwọ.

Alli-Macaulay ni ti awọn omo Naijiria ba ti fa igbo tan ni wọn ma n lọ si ori ẹrọ ayelujara lati lọ sọ isọkusọ.

Nitori naa a gbọdọ ko awọn ọdọ wa lati ko ara wọn ni ijanu ati bi o ṣe yẹ ki wọn huwa lawujọ.

Eyi ni ohun mẹwaa to yẹ kẹ ẹ mọ nipa Arabinrin Asofin Mojisola Alli-Macaulay;

Mojisola Alli-Macaulay

Oríṣun àwòrán, Mojisola Alli-Macaulay

  • Ọrukọ rẹ ni Mojisola Kehinde Alli-Macaulay AKA Mama Amuwo
  • Abilẹko to si ti bi awọn ọmọ ni
  • Ọmọ ọdun mẹtalelogoji ni arabinrin naa
  • Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹwaa, ọdun 1977 ni wọn bi
  • Agbegbe Surulere, ni ipinlẹ Eko ni wọn ti bi
  • O lọ si ile iwe alakọbẹrẹ Festac Primary School V (1984-1990), Subola Nursery And Primary School Festac (1982-1984),
  • Arabinrin Mojisola Alli-Macaulay lọ si ileewe Girama Festac Girls' Secondary School (1990-1993)ati Navy Town Secondary School (1993-1995)
Mojisola Alli-Macaulay

Oríṣun àwòrán, Mojisola Alli-Macaulay

  • Bakan naa lo lọ si ileewe giga Lagos State University to si kẹkọ jade ni ọ̣dun 2015 (History and International Relations) ati ileewe giga The Open University Milton Keynes, Upon Tyne Uk (2002-2003),
  • Arabinrin Mojisola Alli-Macaulay ti gba iwe eri Diploma In Social Science UK 2002-2003, amọ o si n kẹkọ lati gba iwe ẹri imọ ofin ni University of Lagos,
  • O ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọroyin ni ileeṣẹ MITV/STAR FM,
  • O ṣiṣẹ gẹgẹ bi Ọga Ẹka Idokowo Ileeṣẹ D.R. Marketing & Communications,
Mojisola Alli-Macaulay

Oríṣun àwòrán, Mojisola Alli-Macaulay

  • Akọroyin ni ileese Radio Lagos/Eko FM 89.75, ati amojuẹrọ ni ileeṣẹ Continental Broadcasting Service (TVC/RC)
  • Arabinrin Mojisola Alli-Macaulay gẹgẹ bi oloṣelu, o ti jẹ Counsillor ward Bini ọdun 2010- 2013),
  • O jẹ Igbakeji Adari Ile Igbimọ Aṣofin ijọba ibilẹ Amuwo ̣Ọdọfin,
  • Ọmọ Ile Igbimọ Asofin lọwọlọwọ lati ọdun 2019 titi di isinyi NI Arabinrin Mojisola Alli-Macaulay
  • Mojisola Alli-Macaulay fẹran lati ma kawe, rinrinajo ati gbigbọ orin amoriwu.
Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

Ohun tí òṣèré àti aṣòfin, Desmond Elliot sọ táwọn ọmọ Nàìjíríà gbà sí ìbínú

Desmond Elliot

Oríṣun àwòrán, Desmond Elliot/Facebook

Ọrọ Desmond Eliot ni awọn ọmọ Naijiria fi bọnu lori ẹrọ ayelujara nipa ọrọ to sọ lori bi awọn Ologun ṣe da ibọn bo awọn afẹhọnuhan tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa ni Lekki Toll gate,ni ipinlẹ Eko.

Desmond Eliot ni ki awọn gbajumọ lawujọ ati awọn oloṣere ki wọn ye sọrọ kubakugbe lori ayelujara mọ, amọ ki wọn lọ gba kaadi idibo wọn, ki wọn dibo fun ẹni ti wọn fẹ ninu eto idibo to n bọ,a bi ki awọn furawọn dije dupo.

Bakan naa lo ni orilẹede Niajiria yoo di ohun igbagbe ti awọn ọmọ Naijiria ko ba jawọ ninu bi wọn ṣe n ji awọn nkan gbe tabi fi ina si awọn ile.

Elliot gboriyin fun Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin to bu ẹnu atẹ lu ifiyajẹni to waye ni Lekki Toll gate.

''Inu mi dun pẹlu ọrọ ti Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin sọ nipa iṣẹlẹ to waye ni Lekki, amọ o ba oun ninu jẹ pẹlu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣepe, ti wọn tun lo ji ọpa ọba gbe laafin Ọba Ilu Eko.

'Ifiyajẹni, ọrọ kubakugbe ati ikorira ti pọju lorilẹede Naijiria.''

Desmond Elliot

Oríṣun àwòrán, Desmond Elliot

Bakan naa ninu fidio miran to fi lede, o fihan gbangba pe oun ko fọwọsi abadofin to de bi awọn ọmọ eniyan ṣe n sọrọ lori ẹrọ ayelujara, amọ ohun ti oun sọ ni pe, ki wọn ma lo ẹrọ ayelujara lati fi da orilẹede Naijiria ru.

Amọ, gbogbo ọrọ to sọ yi bi awọn ọmọ Naijiria ninu, ti wọn si fi ọrọ gun un lara lori ẹrọ ayelujara.

Ọpọlọpọ awọn to sọrọ to fi mọ Davido ni '' igbagbọ awọn ninu Desmond Eliot ti dopin, pẹlu ọrọ iranu to sọ jade lẹnu''.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bakan naa ni awọn eniyan kesi awọn ara Surulere lati dibo yọ ọ kuro ni ipo, nitori ko ṣe ifẹ awọn araalu mọ.

Gbajugbaja oṣere ni Desmond Eliot ko to di wi pe wọn dibo yan an gẹgẹ bi aṣofin to soju ẹkun Surulere ni Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá