How to apply for Nigeria Youth Investment Fund: Wo ibi láti mọ̀ síi nípa àwọn ọ̀dọ́ tó máa ri owó náà gbà

Oríṣun àwòrán, @Emefiele
Banki apapọ Naijiria ti a mọ si Central Bank ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori irufẹ awọn to maa ri gba ninu owo iranwọ ti o jade yii.
Wọn ni owo naa wa fun awọn ọdọ to nilo iranlọwọ ṣugbọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mejidinlogun si ọdun marundinlogoji lọ.
Awọn to lẹtọ si owo iranwọ N75 biliọna naa lasiko yii ni awọn ti iṣẹ wọn nii ṣe pẹlu:
- Awọn agbẹ olohun ọsin ati oko ounjẹ
- Awọn ti iṣẹ wọn nii sẹ pẹlu imọ ẹrọ ati tikinọlọji
- Wo àfiwé owó oṣù Ọlọ́pàá Nàìjíríà pẹ̀lú akẹgbẹ́ wọn lókè òkun
- Wo awọn iroyin manigbagbe to waye ni ọsẹ yii
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́
- England kéde ìséde ọ̀sẹ́ mẹ́rin míràn láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ Covid 19
- Sanwo Olu àti Okowa dẹwọ́ ìséde ní Eko àti Delta pẹ̀lú àlàyé tuntun
Wọn ni awọn ti iṣẹ wọn ni i ṣe pẹlu irin ajo afẹ, ile kikọ, ati eto ilera laiyọ karakata silẹ.
Wọn ni ki awọn eeyan to ku lọ ni suuru nitori pe eto naa maa kari gbogbo awọn to ba nifẹ sii laipẹ.
Erongba ijọba ni lati yanju iṣẹ to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta laarin ọdun 2020 si ọdun 2023.
Bakan naa ni wọn salaye pe awọn ẹgbẹ alajẹṣẹku ti wọn forukọ silẹ pẹlu ijọba to jẹ ti awọn ọdọ naa yoo jẹ ninu anfani yii.
Awọn ẹnikọókan to forukọ silẹ naa yoo jẹ ninu anfani ọhun.
Wo bí o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ láti gbà nínú N75b tí ìjọba fẹ́ ẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ láti dá iṣẹ́ sílẹ̀
Ìjọba ti ṣí ojú òpó fún àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ ẹ dá iṣẹ́ sílẹ̀
Ijọba Naijiria ti ṣi oju opo ayelujara silẹ fun awọn ọdọ orilẹ-ede naa lati fi orukọ silẹ fun owo iranwọ.
Owo naa ni wọn pe ni Nigeria Youth Investment Fund (NYIF).
Owo naa to jẹ biliọnu marundinlọgọrin lowa fun awọn ọdọ to ba fẹ ẹ da iṣẹ ti ara wọn silẹ.

Oríṣun àwòrán, federal ministry of info&culture
Ileeṣẹ ijọba fun awọn ọdọ ati idagbasoke ere idaraya,lo ṣe agbatẹru eto yii, pẹlu ajọṣepọ banki apapọ, to gbe owo silẹ.
Awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn si wa laarin ọdun mejidinlogun si marundinlogoji, to ni erongba okoowo ti wọn fẹ ẹ ṣe ni eto naa wa fun.
- Oluwo ti ìlú Iwó kìí ṣe ẹgbẹ́ Àtaọjà Osogbo - Alaafin ìlú Ọ̀yọ́
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá
- Aàbò tó péye yóò wà fún àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Owatapa ti Itapa Ijesha, Wolii Olapade Agoro jáde láyé
Ẹnikọọkan wọn sile kọwe beere fun owo to to ẹgbẹrun lọna ọtalerugba din mẹwaa (250,000) si miliọnu marun-un Naira.
Lati fi orukọ silẹ, ẹ lọ si oju opo ayelujara nyif.nmfb.com.ng fun ẹkunrẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Federal ministry of indo&culture
Wo bi wa a ṣe fi orukọ silẹ
Lọ si oju opo ayelujara nyif.nmfb.com.ng
- Tẹ bọtinni ti wọn kọ 'apply here' si, ni oju ewe to ba kọkọ ṣi
- Fi orukọ rẹ silẹ, pẹlu nọmba BVN rẹ, si aaye to yẹ
- Lẹyin naa ni ki o kọ akọsilẹ nipa ọjọ ori rẹ, nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ, adirẹsi rẹ, ipinlẹ ti o ti wa, ati imeeli rẹ, pẹlu awọn nkan miran.

Oríṣun àwòrán, @NG
- Yoo gbe ọ lọ si oju ewe to kan lati sọ nipa iwe ẹri ileewe ti o wa lọwọ rẹ.
- Abala to kẹhin ni wa a ti yan ibudo ti o ti fẹ ẹ gba idanilẹkọ rẹ.
Fi si ọkan pe ọfẹ ni iforukọ silẹ ati idanilẹkọ
Ori ayelujara ni idanilẹkọ naa yoo ti waye fun ọjọ marun-un gbako.
- Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ déé fáwọn ọmọ Ọlọ́pàá tó kú lásìkò EndSARS, Gómìnà Sanwo-Olu kéde
- Wo bi o ṣe le fi orúkọ̀ sílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ìjọba Nàìjíríà fún ọdún 2021/2022
- Ṣé o mọ̀ pé o leè forúkọ̀ iléeṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́? Oníṣẹ́ àdáni 250,000 ni ìjọba ṣe ìlànà yìí fún
- Ẹ gbọ́ ohun tí Desmond Elliot sọ lórí ayélujára tó bí àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú
- Àwàdà tàbí óótọ́, kì lò f'ẹkún Kọmíṣọ́nnà ìlera Kogi lórí amóhùnmáwòrán?

















