Olapade Agoro: Olùdíje dùpo aàrẹ Nàìjíríà rí, Owatapa ti Itapa Ijesha, Wolii Olapade Agoro jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
Olapade Agoro jade laye ni oru mọju ọjọ kinni, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
A bi Wolii Olapade Agoro lọjọ kẹsan an, oṣu kẹwaa, ọdun 1943 ni abule Ajibabi ni ilu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo ni guusu Iwọ oorun Naijiria
Olapade jẹ ọmọ ile ori ade nitori pe baba rẹ jẹ ọmọ Ọba Atapami ni ilu Itapa Ijesha.
Omo Oba Tapa Joshua Alaba Agoro ni baba rẹ nigba ti iya rẹ si jẹ Dorcas Oyejola Asabi agoro to tun jẹ iya ni Isreli ni ile Oluwa.
Olapade Agoro lọ sile iwe alakọbẹrẹ ti girama ati Enfield Training Centre, College of Technology ni Willesden London ati Gateshead Co Durham.
Bakan naa lo kawe sii ni fasiti Carlifornia Western University, fasiti ọlọgba ẹranko nibiti sanmọnti gbe dunlẹ ni Ibadan ati ni fasiti California Coast University nibi to ti gba oye ọmọwe ninu interdisciplinary engineering.
Lọdun 1982 ni wọn fi jẹ Owa 'Tapa ti Itapa Ijesha ni ipinlẹ Osun ni iwọ oorun guusu Naijiria.
Omowe Olapade Agoro je okan lara awọn oju ti ọpọ n wo ninu iṣelu Naijiria gẹgẹ bi agba to moye.
- Sanwo Olu àti Okowa dẹwọ́ ìséde ní Eko àti Delta pẹ̀lú àlàyé tuntun
- Ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Adelé Ọba Alade Idanre ló rí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Ọba Aroloye
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Aàbò tó péye yóò wà fún àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá
Olapade Agoro ni awọn ile iwe loriṣiirisii yatọ si pe o da ẹgbẹ oṣelu National Action Council silẹ.
Awọn ọmọ ati Naijiria lapapọ lo n ṣe idaro Wolii Olapade Agoro bayii.
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Wo àfiwé owó oṣù Ọlọ́pàá Nàìjíríà pẹ̀lú akẹgbẹ́ wọn lókè òkun
- Orúkọ àwọn tó yege láti darapọ̀ mọ́ ikọ̀ Amotekun ní ìpínlẹ̀ Oyo ti jáde
- Gbajúgbajà òṣèré tó ṣe fíìmù James Bond tí jáde láyé lẹ́ní ọdún 90
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́

Oríṣun àwòrán, @Alhaja Adeola Agoro
Owatapa ti Itapa Ijesha, Wolii Olapade Agoro jáde láyé
Gbajugbaja oloṣelu to tun jẹ Wolii ni, Omowe Olapade Agoro ti dagbere faye pe o digboṣe.
Ebi oloogbe naa lo fidiẹ mulẹ pe lẹyin aisan ranpẹ ni iku wọle mu Wolii naa to dije dupo aarẹ Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu National Action Council (NAC).

Oríṣun àwòrán, @Alhaja Adeola Agoro
Loru mọju oni ọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu kọkanla, ọdun 2020 ni Wolii naa jẹ Olorun nipe.
Alhaja Adeola Agoro JP to jẹ ọmọ oloogbe naa fi soju opo facebook rẹ pe iku ti wọle mu ẹni rere naa lọ.

Oríṣun àwòrán, @Alhaja Adeola Agoro
- Àwọn jàǹdùkú ya bo àfin Ọba ní Alade Idanre, wọ́n lu Adele ní ìlù bàrà
- Sanwo Olu àti Okowa dẹwọ́ ìséde ní Eko àti Delta pẹ̀lú àlàyé tuntun
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ṣòfò nibi ìjàmba tó wáye ni Akungba nìpińlẹ̀ Ondo
- England kéde ìséde ọ̀sẹ́ mẹ́rin míràn láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ Covid 19
- Èèyàn 162 ló kó àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé
Wolii Olapade Agoro jẹ ẹni ọdun mejidinlọgọrin ki ọlọjọ to mu u lọ.
Saaju iku rẹ lo ti n sọrọ rere nipa iyansipo Asiwaju Bola Tinubu gẹgẹ bii aarẹ labẹ APC ni 2023.
Oun naa ni oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu NAC.
Ọpọlọpọ ọmọ ni awọn ọmọ olooku fi sori ayelujara ti wọn si fi n daro ẹni wọn to lọ.

Oríṣun àwòrán, @Alhaja Adeola Agoro

















