AFCON Qualifier: Kò séwu fún gbogbo àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki

Oríṣun àwòrán, @daily_trust
Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti sọ pe abo to peye yoo wa fun gbogbo awọn agbabọọlu atawọn ero iworan ti yoo wa nibi ifẹṣewọn laarin ikọ Super Eagles ati Leone Stars ti orilẹ-ede Sierra Leone lọsẹ to n bọ.
Ifẹsẹwọnsẹ naa to jẹ igabradi idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika, AFCON, ti yoo waye lọdun 2021 ni yoo waye ni papa iṣẹre Samuel Ogbemudia ni ilu Benin.
Bakan naa ni ifẹsẹwọnjsẹ to lamilaaka akọkọ ti yoo waye ni papa iṣẹre naa lati igba ti wọn ti ṣatunṣe rẹ.
O tun jẹ ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka ti ikọ Super Eagles yoo gba lati igba ti ajakalẹ arun Coronavirus ti bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @NGSuperEagles
Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye lọjọ kẹtala, oṣu kọkanla, ọdun 2020, lẹyin ọjọ ti iburawọle gomina Obaseki fun saa keji gẹgẹ bii gomina.
Olubadamọran pataki fun gomina ọhun lori ọrọ to n lọ, Crusoe Osagie sọ pe ijọba ipinlẹ naa ti ṣetan lati dabo bo gbogbo eeyan ti yoo peju sibi ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "idunnu wa ni lati ṣagbatẹru igbaradi idije AFCON 2021 laarin ikọ Super Eagles ati Leone Stars ni papa iṣẹre Ogbemudia."
- Agbára wa kò ká àrùn Covid-19 mọ́ - Ìjọba ilẹ̀ Amẹrika
- Ṣé Biden lè fẹ̀yìn Trump kó di ààrẹ America tó kàn?
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Owatapa ti Itapa Ijesha, Wolii Olapade Agoro jáde láyé
- Àwọn jàǹdùkú ya bo àfin Ọba ní Alade Idanre, wọ́n lu Adele ní ìlù bàrà
- Sanwo Olu àti Okowa dẹwọ́ ìséde ní Eko àti Delta pẹ̀lú àlàyé tuntun










