Everton vs Liverpool: VAR gba Everton sílẹ̀ lọ́wọ́ ogun ẹ̀yìn Liverpool, ọ̀mì ayò 2-2 ní wọ́n gbá ní Merseyside

Mo Salah

Oríṣun àwòrán, Premierleague.com

Salah gba goolu kan wọle eyi to jẹ ọgọrun goolu rẹ ni idije Premiership ṣugbọn alayo meji meji ni Liverpool at Everton ta.

Ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni gbagede ibuba Everton to wa ni Merseyside pari pẹlu awọn oniruuru arisọ to kan ikọ mejeeji.

Mane, atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lo kọkọ mi awọn nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹta amọṣa, Michael Keane daa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa de iṣẹju kọkandinlogun.

Omi alayo kọn yii ni wọn gbe wọ isinmi aarin ifẹsẹwọnsẹ naa ki Liverpool to tun fi goolu kan sii nigba to di iṣẹju kejilelaadọrin lati ẹsẹ Mo Salah.

awọn agbabọọlu Everton ati Liverpool

Oríṣun àwòrán, Premierleague.com

Iran ko ti tan ni ifẹsẹwọnsẹ naa nitori lẹyin iṣẹju mẹsan si asiko goolu yii ni Calvert-Lewin daa pada bi owo baba ijẹbu fun Everton.

Richarlison, agbabọọẹu Everton gba kaadi pupa ti wọn fi lee jade ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Iroyin ayọ ti ko ba jẹ fun Liverpool ni ipari ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti Henderson gba goolu kan wọle ṣugbọn ayẹwo igbalode VAR dawọn lẹkun idunnu naa.

Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii, Everton lo ṣi n lewaju loke tente tabili liigi ilẹ Gẹẹsi bayii ti liverpool si n tẹlee pẹly ami mẹwaa.