Deontay Wilder: Wilder ní òun sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ lẹ́yìn tí Fury fẹ̀ṣẹ́ já iṣan ọwọ́ rẹ̀ loṣù kejì

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iya ko to iya ni ọmọde maa sọ pe ko ni dara fun ẹni to lu oun. Agbaọjẹ abẹṣẹ ku bi ojo, Deontay Wilder lo sọ pe oun si n gba itọju lẹyin oṣu mẹjọ ti Tyson Fury ti fẹṣẹ dara si oun lara.
Wilder oun ko lanfaani lati ṣe igbaradi kankan bayii nitori oun ni lati ṣe iṣẹ abẹ nitori ipalara ti oun ni lori iṣan ọwọ oun nigba ti o koju Fury.
Wilder to jẹ abẹṣẹ ku bi ojo ọmọbibi ilẹ Amẹrika fidi rẹmi ninu ija fun igba akọkọ nigba ti oun ati Futy waako loṣu keji ọdun 2020 yii niluu Las Vegas l'Amẹrika.
- Olivier Giroud fi àràmọ̀ndà góòlù méjì ṣayẹyẹ ìfẹsẹ́wọnsẹ̀ ọgọ́rùn ún tó gbá fún France
- Gómìnà Seyi Makinde bá ẹbí Isiaq Jimoh tó kàgbákò ikú òjijì dárò
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- N kò sọ fún ìyá mi kí ń tó lọ sílé BB Naija - Laycon
- Ó sàn fún mi kí n máá tíì lọ́kọ báyìí ju kí n lọ́kọ ṣùgbọ́n...- Nkechi Blessing
- Bí èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo se ń jáde rèé..
O yẹ kawọn mejeeji tun jọ koju ara wọn lẹẹkan si lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keje ṣugbọn iṣede ajakalẹ aarun coronavirus ko jẹ ki ija naa waye.
''Mo ti n gbadun bọ diẹ diẹ, ohun kan ti mo n ro lasiko yii ni lati gbadun pada,'' Wilder lo sọ bẹẹ.
Wilder ti inagijẹ rẹ n jẹ Bronze Bomber sọ pe oun yoo bẹrẹ igbaradi kete ti oun ba ti gbadun tan.
Nigba naa ni mo maa raye lati bẹrẹ si ni ṣe ohun ti mo fẹran lati maa ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wilder ni oriṣiiriṣii ounjẹ loun n jẹ lọwọ yii pẹlu afẹsọna atawọn ọmọde to rọgba yi oun ka.
O ni oun ko le ṣe aroye nipa ohun ti oun n la kọja lasiko yii, nitori gbogbo agbaye lo n la oriṣiiriṣii nkan kọja bayii fun igba akọkọ.
Ṣugbọn Wilder si gbagbọ pe oun si le ba Fury ja ki ọdun 2020 to pari bo tilẹ jẹ pe ko tii gbadun ọwọ rẹ tan.












