BB Naija winner 2020: Laycon ní òun kò lérò pé òun le mókè, àgbéga orin lòun bá lọ sílé náà

Oríṣun àwòrán, Instagram/itslaycon
Ẹni to gbegba oroke ninu idije BB Naija fọdun 2020, Olamilekan Agbeleshebioba, ti gbogbo eeyan mọ si Laycon ti kede pe oun ko bun iya oun gbọ, ki oun to lọ kopa ninu eto naa.
Laycon, ẹni to sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori akanse eto kan ni ikanni BBC Yoruba, salaye pe eeyan meji ni oun fi igbesẹ oun naa to leti, eyiun Maneja ati ẹgbọn oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Ìdí tí Gúúsù Akure, Owo àti ìwọ̀orun Ondo yóò fi sọ ẹni tí yóò jáwé olúborí nínú ìbò gómìnà Ondo
- Kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ Okonjo-Iweala ń súnmọ́ ipò olórí WTO bọ̀
- Bode George ní Fayose gọ̀, ó fẹnu họra, Fayose ní ''ẹ ò lè pa mí bí ẹ ṣe pa Bola Ige
- Ènìyàn 5, ilé 25 ilé ìtajà 16 àti àwọn ǹkan mírà lo bá ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà rìn.
- "Ọkùnrin kọ́ ló ra jeep fún Iyabo Ojo, òógùn ojú mi ni mo fi rà á fun"
- Kanu Ejike fipá bá ọmọ ọdún méje lò pọ̀ nínú sọ́ọ̀bù ìyàwó rẹ̀
Amọ o ni o da oun loju pe iya oun n se atilẹyin fun oun lasiko ti oun wa nile BB Naija naa, to si maa n gbadura fun aseyọri oun nitori pe gbogbo ohun ti oun ba dawọle, ni iya oun maa n sugba rẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/itslaycon
Laycon, ẹni to salaye pe oun ko ni lero rara pe oun le jawe olubori ninu idije naa, fikun pe oun naa gbero lati kopa lori eto naa, ki oun lee se agbelarugẹ orin ti oun n kọ ni.
Nigba to n mẹnuba ọjọ manigbagbe fun lasiko to wa lori eto BB Naija, Olamilekan ni ayajọ Johnny Walker ati Guinness stars, ti oun, Vee ati Nengi wa ni isọri kannaa, ni oun ko le gbagbe laelae.
Nigba ta bi Laycon nipa obinrin to n pariwo lori ayelujara pe oun ti loyun fun, Olamilekan ni laelae, ọrọ ko ri bẹẹ, irọ si lo wa nidi rẹ nitori obinrin kankan ko ni oyun fun oun.
Ẹ wo fidio ifọrọwerọ BBC Yoruba pẹlu Laycon naa ni oju opo wa ni Facebook wa:
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe, ọrẹ oun ni Vee, bẹẹ ni ko si ọjọ kankan to jẹ ọjọ ibanujẹ fun oun lasiko ti oun wa nile BB Naija.
Awọn ohun to ti ṣẹlẹ si Laycon saaju asiko yii:

Oríṣun àwòrán, NAirametrics
Dapo Abiodun yan Laycon ní aṣojú pẹ̀lú ẹ̀bún ₦5m àti ilé oníyàrá mẹ́ta
Saaju la ti sọ fun yin pe, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti fun yan oludije to bori ninu ile BB Naija lọdun yii, Olamilekan Agbeleshebioba, ti ọpọ eeyan mọ si Laycon gẹgẹ bi asoju fun ipinlẹ naa.
Bakan naa ni gomina Abiodun tun fun Laycon ni ẹbun ile oni yara mẹta ati owo to to miliọnu marun naira gẹgẹ bii owo iwuri lati mọ riri rẹ.
Gomina ipinlẹ Ogun sisọ loju ọrọ yii lasiko to n gbalejo Laycon ni ọọfisi rẹ to wa ni Oke Mọsan nilu Abeokuta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé iṣẹ́ ń dúró de akẹ́kọ̀ọ́ tó yan iṣẹ́ olùkọ́ láàyò ní fásitì?
- Adájọ́ sọ wòlíì Sotitobire àtàwọn márùn-ún míì sẹ́wọ̀n gbére!
- Kìí ṣe emí ni mó ràn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ mi tó sọ̀rọ̀ abùkù sí FIBAN níṣẹ́- Wasiu Ayinde
- ENDSARS: Ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, ẹ ṣè ìrànwọ́ irinṣẹ́ fáwọn ọlọ́pàá- Naira Marley bẹ̀bẹ̀
- Ẹ̀wọ̀n ni wàá gbẹ̀yìn sí, kò sí bóo ṣe dọ́gbọ́n tó - Seyi Makinde wa ègúná ọ̀rọ̀ lé Fayose
- Ibadan ń jó àjórẹ̀yìn láàrin ẹgbẹ́, ẹ fún wa ní ìpínlẹ̀ tiwa - Kola Balogun bẹ ilé aṣòfin
Gomina Abiodun ni "Emi funra mi n foju sọna lati ba ọ sisẹ gẹgẹ bi awokọse iwa rere, aseyọri, abuda gidi, iwa tutu ati ododo, eyi tii se ara abuda ijọ̀ba ipinlẹ Ogun, koda, agbegbe Odeda lo ti wa."
O wa gba Laycon nimọran lati lo agbara rẹ fun didẹkun awọn iwa kotọ lawujọ, awọn iwa ti kii se ti ọmọluabi atawọn iwa ibi miran.
Ìjọ́ba ìpínlẹ̀ Ogun náà ti gbóríyín fún Laycon gẹ́gẹ́ bíi ògidì ọmọ Ogun sùgbọ́n dandan ní owó orí sísan
Ijoba ipinle Ogun naa ti ki Lekan ku oriire pelu erongba lati jo sise papo sii lodun to m bo.
Won gboriyin fun un gẹ́gẹ́ bii ogidi ọmọ Ogun to tẹpa mọsẹ

Oríṣun àwòrán, OGIRS
Ijọba ipinlẹ Ogun se sadankata Lekan pe omọ to se e fi yangan ni fun awọn ọdo asiko yii,
Koda, won ti ranṣẹ ikini ku orire si 'ọmọ ologo' Laycon, to jẹ owo ati ẹbun BBNaijia to kasẹ nilẹ lọjọ Aiku.
Ijọba Ogun ko danu duro lori ikinni nikan, wọn tun ni ko ma gbagbe lati san owo ori rẹ fun ọdun 2021 ninu owo to jẹ naa.
Ati pe inu awon si maa dun lati jọ́ dowopọ sii lodun to m bo
- Ayuba Sarafa, Olọ́kadà kan tó jẹ́ eni ọdún 22 pokùnso ní Ibadan
- N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye
- Wo bí ìtàkurọ̀sọ láàrin Donald Trump àti Joe Biden yóò ṣe wáyé
- Ilé ẹjọ́ gíga ní kí òsìsẹ́ First Bank tẹ́lẹ̀ lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 98 lórí ẹ̀sùn pé o jí mílíọnù 49 àti $368, 000 níbẹ̀
Ki lo ti kọ́kọ́ sẹlẹ̀?
Laycon, kú oríire àmọ́ bá ń kó owó orí nínú ẹ̀bùn rẹ nílé BB Naija - Ìjọba Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter/jidesanwoolu/BBNaija
Ijọba ipinlẹ Eko ti ranṣẹ ikini ku orire si 'ọmọ ologo' Laycon, to jẹ owo ati ẹbun BBNaijia to kasẹ nilẹ lọjọ Aiku.
Ijọba Eko ko danu duro lori ikinni nikan, wọn tun ni ko ma gbagbe lati san owo ori rẹ fun ọdun 2021 ninu owo to jẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Miyetti Allah ní kí wọn wọ́gilé Amotekun, Sunday Igboho yarí
- Boko Haram gbọ̀nà àrà yọ, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló so àdó olóró mọ̀ láti kọlu Gómìnà Borno
- Ìṣòro jíjẹ́ ìyá n dáàgbé ló sọ mí di àtúnbí krístíẹ́nì - Remi Tinubu
- Kí ló ń fa wàhálà láàrín Kunle Afolayan àti Mike Ezuruonye lórí ayélujára?
- Ọmọ ṣá bàbá rẹ̀ pa, ohun tó sọ pé ó ṣe nìyí...
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san N50m fún obìnrin tó fìyà jẹ
- Mi o fi ìgbà kankan sọ pé Buhari ni yóò jẹ ààrẹ kẹ́yìn ní Nàìjíríà- Akintoye
Loju opo Twitter ajọ to n mojuto gbigba owo ori nipinlẹ Eko LIRS ni wọn fi ọrọ yii sọwọ, lati le ran Laycon leti pe, awọn n duro de owo ori rẹ ninu owo to gba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọrọ yii ti n mu ki awọn eeyan maa sọ orisirisi ero wọn nipa rẹ lori ayelujara.
Bi awọn ṣe n sọ pe o yẹ tabi ko yẹ ki Olamilekan san owo ori, lawọn miran n jiyan lori iye owo ori ti Laycon jẹ gangan.
Koda, awọn miran n gba a ni imọran lati rọra na owo naa, ko ba ma na owo ori to yẹ ki o san pọ mọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ki ni ofin sọ nipa gbigba owo ori lori owo idije ti eeyan ba jẹ
Naijiria ko yatọ si awọn orileede mii lagbaye ti awọn eeyan ti n san owo ori lori owo tẹtẹ tabi idije idaraya ti wọn ba jẹ.
Ni Naijiria ko si agbelewọn to yatọ lori owo ori awọn elere idaraya tabi awọn to n ṣe iṣẹ amuludun.
Owo ori ti wọn n san ko yatọ si eyi ti onikaluku n san lori owo to wọle fun lọdun.

Oríṣun àwòrán, Twitter/BBNaija
Fun idi eyi Laycon yoo ni lati san owo ori lori owo to jẹ ninu idije yi ati apapọ iye ẹbun to ri gba ayafi eleyi ti ijọba ba yọnda fun labẹ ofin.
Amọ ṣa ijọba ipinlẹ ibi to ba ti jẹ owo bi apẹrẹ ti Laycon to waye ni Eko yi ni o lẹtọ lati gba owo naa lori apapọ owo ti Laycon ba pa wọle lọdun .













