Tax: Kíni ìdí tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò fi rí owó orí gbà?

Lagos oil platforms

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Epo bẹtiró ni ó mú owó wọlé jùlọ
    • Author, Reality Check team
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba Naijiria ti figbe sita pe orilẹ-ede naa lee dojukọ ipenija iṣuna, bi ko ba wa atunṣe si ọrọ owo ori gbigba.

Owo ti ijọba orilẹ-ede naa n na ti le ni ilọpo meji, ati pe owo gbese to n san ti ga ju ti tẹlẹ lọ.

Bakannna ni owo to n wọle sapo ijọba ti din ni iye ti o to ida marundinlaadọta ida ọgọrun lati ọdun 2015.

Toun ti bẹẹ, ijọba Naijiria n gboriyin fun ajọ to n ri si ọrọ owo ori lorilẹ-ede naa (FIRS) fun akitiyan rẹ lati mu ki iye awọn to n san owo ori le sii ni ilọpo meji, lati ọdun 2015.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Gbara ti wọn fi ọrọ yi sita lawọn kan lori ẹrọ ayelujara ti beere boya ọrọ ti ijọba kede ri bẹẹ lootọ.

Koda, wọn fi kun pe, ti o ba jẹ pe lootọ ni awọn to n san owo ori ti le sii, ki lo de ti ayipada ko ti de ba awọn ohun amayedẹrun bii ọna oju popo, eto ẹkọ ati eto ilera?

Ọna lati jẹ ki awọn to n san owo ori di pupọ sii

Gẹgẹ bi ọrọ ti ijọba fi lede, miliọnu mọkandinlogun ọmọ Naijiria lo san owo ori sapo ijọba lọdun 2018.

Ọrọ ti banki agbaye sọ lọdun naa ni pe, marundinlaaadọrin ọmọ Naijiria lo nipa lati sanwo ori - bi o tilẹ jẹ pe iye awọn to n sanwo ori ti gbe pẹli sii, ko tii to ida ọgbọn awọn to n sanwo ori.

Ijọba si ti n mura mọ awọn eeyan ti o lee sanwo ori sugbọn ti wọn kọ lati san an.

Owó ilẹ̀ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nàìjíríà kò rí owó orí gbà

Ni nkan bi ọdun meji sẹyin, ijọba Naijiria fun awon to kọ lati sanwo ori ni anfani ọdun kan pe ki wọn wa san owo ori ti wọn ti jẹ latẹhin wa.

Igbesẹ yi jẹ ọna akan gbogi fawọn onigbese naa lati ma ba sanwo itọnran ati ki wọn ma ba foju ba ile ẹjọ.

Banki agbaye tubọ sọ pe ninu awọn onigbese yi, ida mẹjọ pere lo san owo ori ti wọn jẹ laarin gbedeke asiko ọdun kan ti wọn la kalẹ.

Awọn ọmọ Naijiria naa ko ṣadede kọ lati ma san owo ori.

Igbagbọ ti ọpọ ni si ijọba ni pe ijọba kii na owo naa lori eto ilera, eto ẹkọ ati awọn ohun amayedẹrun miran.

Wọn gbagbọ pe awọn kan ni yoo ko owo naa sapo.

Owo epo betiro ja walẹ

Iṣoro ti ijọba Naijiria n dojukọ bayii ni bi owo epo bẹtiro ṣe ja walẹ, ati ipadasẹhin ọrọ aje to ṣẹlẹ lorilẹ-ede naa lọdun 2016.

Owo agba epo bẹtiro ja walẹ lati ẹẹtalelaaadọfa dọla si ẹẹrinlelaadọta dọla le diẹ lọdun 2017.

Orilẹ-ede Naijiria lo n pese epo bẹtiro julọ l'Afirika laarin ọdun 2012 si 2014, ida ẹtadinlọgọta owo to wọle sapo ijọba orillẹ-ede naa lo wa lati ẹka epo.

Sugbọn eyii ja walẹ laarin ọdun 2016 si ọdun 2018.

Ijọba si sti sọ pe, owo ori to n wọle ti gbe pẹli sii lati ọdun 2015.

Ṣugbọn ọrọ ti ajọ agbaye gbe jade lọdun yii fihan pe, lọdun 2018, alafo to wa laarin owo ori VAT ti Naijiria ri gba ati iye ti wọn ro pe wọn o rigba - lo wa lara awọn eyi to pọ ju nilẹ adulawọ.

VAT gap in selected African countries. . Assumes all private consumption would have paid VAT.

Orilẹede Naijiria sọ pe, oun n tiraka lati gba owo ori lati awọn ọna miran, bii lori karakata lori ẹrọ ayelujara. Ijọba naa ti wi pe, oun yoo kan nipa fun awọn ile ifowopamọsi lati maa gba owo ori lori karakata ti awọn ọmó orilẹ-ede naa ba n ṣe lori ẹrọ ayelujara, lati oṣu kini ọdun 2020.

Agbejade kan lati Fasiti Oxford sọ pe, owo to wọle lọna ti kii ṣe lati ori epo bẹtiro ti le sii, sugbọn ere towa lori awọn owo naa ni ọwon gogo ti sọ di yẹpẹrẹ.

Bawo ni o ṣe rilagbaye?

Awọn iṣiro kan fihan pe, orilẹ-ede Naijiria jẹ ọkan ninu awọn orilẹede ti owo ori wọn kere julọ lagbaye.

Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ Iṣọkan ifọwọsowọpọ ati idagbasoke lagbaye fi lede, ida marun pere ninu awọn to le san lo n san owo ori ni Naijiria.

Ajọ naa tun sọ wi pe, iwọn owo ori ti a'won eeyan san, si bii orilẹ-ede ṣe n ṣe ọrọ aje si ni South Africa jẹ ida mọkandinlọgbọn, ti orilẹ-ede Ghana jẹ ida mejidinlogun, ti Egypt jẹ ida marundinlogun, nigbati ti Kenya jẹ ida mejidinlogun.

Nigeria's low tax take. . *average of 36 OECD members.

Gẹgẹ bii iwadii ti ajọ banki agbaye ṣe, wọn sọ pe, iwọn owo ori ti awọn eeyan san ni Naijiria lọdun 2016 kere diẹ ni ida mẹrin.

Sugbọn lọdun 2017, ipin naa gbe pẹli diẹ sii bi ida marun din diẹ, gẹgẹ bi ọrọ ti ijọba Naijiria fi ranṣẹ si BBC.

Ileeṣẹ wa ko ni ipin ti ọdun 2018, sugbọn a lee sọ pe, ida marundinlogun lajọ banki agbaye fọwọsi pe orilẹ-ede nilo lati mu ki eto ọrọ aje wọn dagba soke ati lati din iṣẹ ku.

Bawo a ṣe lee ṣe imugboro owo ori gbigba?

Ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede to ṣẹṣẹ ndagbasoke lagbaye ni owo ori wọn kere si iye ọrọ aje wọn, awọn ifilede to n jade laipẹ yii fi han pe, o kere ju ida marundinlogun ti ajọ banki agbaye fi lọlẹ lọ.

Bernardin Akitoby, ti o jẹ igbakeji adari kan ni ajọ IMF sọ pe, owo ori orilẹ-ede to ti ni ilọsiwaju ma n jẹ bii ida ogoji si apapọ ọrọ aje wọn.

Ọgbeni Akitoby ni, ko si ọna kan sọsọ lati mu ki owo ori gbigba gboro sii, sugbọn, alee ri ẹkọ diẹ kọ lara awọn orilẹ-ede ti o ti ṣaṣeyọri ninu owo ori gbigba, bii:

  • Ipinu ijọba lati gbogun ti iwa awọn ara ilu lati maṣe sanwo ori
  • Ọna to rọrun lati san owo ori
  • Fifi owo ori ṣe karakata
  • Lilo imọ ẹrọ fun owo ori gbigba

Ajọ IMF ni, ṣiṣe atunṣe ẹka owo ori ni lórilẹ-ede Naijiria lee mu ki alekun de ba eto owo ori gbigba ni bii ida mẹjọ.

Presentational grey line
Reality Check branding