Nigeria Army: Kò sí òtító nínú ọrọ náà pé Boko Haram gba owó lọwọ wa

fighting boko

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Nigeria Army: Kò sí òtító nínú ọrọ náà pé Boko Haram gba owó lọwọ wa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iroyin ni Boko Haram gba owo lọwọ awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria.

Awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram ni iroyin ni wọn dena gba ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira lọwọ awọn ọmọ ogun ilẹ yii ni opin ọsẹ to kọja.

Iroyin naa sọ pe, koto nla kan ni awọn ẹgbẹ́gun Boko Haram naa gbẹ silẹ de awọn ọmọ ogun naa ni popona Azare si Kamuya ni ipinlẹ Yobe ni ariwa Naijiria.

Lori ayelujara ni iroyin naa ti ni eeyan kan ninu awọn ọmọ ologun naa farapa yanna-yanna ti ọpọ ohun ija si bajẹ kọja aala.

Ninu awọn ohun ija ti awọn ọmọ ologun n ko lọ ni iroyin salaye pe awọn Boko Haram naa tun gba, ti wọn si ko lọ.

Iroyin naa ni wọn gba owo to le ni miliọnu mẹẹdogun lọwọ wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Nigba ti BBC kan si ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria lati fidi iroyin yii mulẹ ni wọn sọ pe irọ funfun balau ni.

Ẹka iroyin ati ifitonileti ni ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ̀ ni ko si ootọ kankan ninu ọrọ naa àti pé ko si bi awọn ọmọ ogun boko Haram ṣe le gbena woju awon ọmọ ogun.

Ni afikun, wọn ni awọn ọmọ ogun ilẹ wa ti gbaradi lati dena gbogbo ọna ti Boko Haram n gba lati ṣe ijamba fun ara ilu.

Oga ologun to ba BBC sọrọ ni pe boko haram ko da ọmọ ogun lọna de ibi pe wọn gba owo ajẹmọnu lọwọ wọn rara.