NURTW: Makinde kò tíì yí àṣẹ rẹ̀ padà lórí i gbígbẹ́sẹ̀ lé NURTW ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Oṣiṣẹ NURTW kan

Oríṣun àwòrán, @ibcityannouncer

Àkọlé àwòrán, NURTW: Makinde kò tíì yí àṣẹ rẹ̀ padà lórí i gbígbẹ́sẹ̀ lé NURTW ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ko sohun to yipada lori ofin to gbẹsẹ le iṣẹ awọn ẹgbẹ awakọ ero, NURTW ni ipinlẹ Ọyọ.

Ninu atẹjade kan ti ajọ amojuto lilọ-bibọ ọkọ nipinlẹ Ọyọ, OYRTMA fi sita ni ọrọ yii ti jẹyọ.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni awọn ti n gbọ finrinfinrin pe awọn eeyan kan ti n ṣe kurukẹrẹ kaakiri lọna ti ko bofinmu ti wọn si n pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ awakọ ero, NURTW nipinlẹ Ọyọ.

Arumọjẹ ti wọn si n ṣe fun awọn araalu atawọn awakọ ẹgbẹ wọn ni pe, aṣẹ ti ijọba fi gbe ẹsẹ le ẹgbẹ naa ti yọ bi ori inu oorun ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019.

Eleyii ti wọn ni o fun awọn lanfani lati tun bẹrẹ si nii da tabi gba garaaji atawọn ibudokọ gbogbo nipinlẹ Ọyọ ti wọn si fi n doju ija kọ awọn oṣiṣẹ ORTMA ati lati da omi alaafia ilu ru.

Ajọ OYRTMA nipinlẹ Ọyọ ko ṣai wa tẹnumọ pe titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ofin ijọba eleyii ti gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde pa ṣi wa sibẹ.

Wọn ni aṣẹ naa gẹgẹ bii alakoso agba fun eto aabo nipinlẹ Ọyọ pa lati gbẹsẹ le eegun ẹgbẹ awakọ ero pe ko gbọdọ ṣẹyọ bayii nipinlẹ naa ṣi wa nikalẹ, ẹnikẹni to ba si fọwọ pa ida aṣẹ naa yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019 ni gomina Seyi Makinde ti wọn ṣẹṣẹ bura fun wọle nigba naa paṣẹ pe eegun ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ naa ko gbọdọ ṣẹyọ mọ fun asiko yii.

Makinde sọrọ naa nitori rogbodiyan ti wọn fẹ maa da silẹ nigba naa nitori ati yii ijọba pada pẹlu ayipada to de ba ijọba nigba naa.

Àkọlé fídíò, Port harcourt Bole: Mi kò mọ́ pé bọ̀ọ̀lì títà lè gbé mi dé ipò yìí láyé mi!