Plane crash: Díẹ̀ ló kù kí bàlúù arìnrìnàjò sílẹ̀ mímọ́ Hajj gbaná ní Minna

Baluu kan ni papa ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ori ko arinrinajo ẹgbẹta o din aadọta yọ ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ori ko ẹgbẹta o din aadọta awọn abọde arinrinajo silẹmimọ Hajj yọ ni Minna.

Eyi ṣẹlẹ nigba ti ọkọ baluu to n gbe wọn bọ wale lati Saudi Arabia lọ fi tipatipa balẹ ni papakọ ofurufu ilu Minna ni ipinlẹ Niger.

Baluu ẹya Boeing 744 naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 5N/DBK la gbọ pe idaamu de ba ọkan lara awọn ẹnjini rẹ bi o ṣe n sunmọ papakọ ofurufu naa.

Ohun ti a gbọ ninu awọn iwe iroyin abẹle ni pe ko seeyan to ṣeṣe tabi ku ninu iṣẹlẹ naa.

Bakan naa la gbọ wi pe orin asalatu ọlọpẹ lo gba ẹnu awọn abọde ilẹmimọ naa kan ni kete ti koowa wọn n sare bọ silẹ lati inu baluu naa.