Lagos Waste management: Ìgbà ọ̀tun dé lóríi èto kólẹ̀kódọ̀tí ní ìpínlẹ̀ Eko

Gomina Sanwo olu nibi ifilọlẹ akoto ikẹgbin nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Thenation newspapers

Igba titun ti wọlu fun eto kolẹ-kodọti ni ipinlẹ Eko pẹlu bi gomina ipinlẹ naa, Babajide Sanwo-olu ṣe jẹjẹ bayii pe eto kolẹkodọti ni ipinlẹ naa yoo rin jinna, si lilo ọna atijọ lati palẹ ẹgbin mọ bayii.

Gomina Sanwo-Olu ni tọọnu ẹru to le ni ẹgbẹrun mẹwa lo n jade ni ipinlẹ Eko lọdun, eyi to ni o gba ki wọn lo imọ igbalode lati fi koju rẹ.

Lasiko to n ṣefilọlẹ akoto ikodọti alawọ buluu ti ajọ kolẹkodọti ipinlẹ Eko LAWMA ṣẹṣẹ gbe kalẹ, ti wọn pe ni LAWMA blue box ni Sanwo-olu sọ ọrọ yii sita.

O ni afojusun ipinlẹ Eko lori eto kolẹkodọti ni lati rii pe yatọ si pipalẹ ẹgbin mọ, wọn tun sọ ẹgbin gbogbo di ajilẹ fun idagbasoke ọgbin lawujọ.

Bakan naa lo ni eto tuntun ti wọn fẹ gbe wọ ilana ipalẹ ẹgbin mọ l'Eko bayii, yoo tubọ mu ki ipese iṣẹ burẹkẹ sii nipinlẹ naa.