Oluwo: Àwọn Alfa ń ‘copy’ mi ni wọ́n ṣe yan Waziri míràn

Oluwo tilu Iwo
Àkọlé àwòrán, Oluwo tilu Ìwo sọ pe òun fẹ di Ọba onilawani (Emir) ilẹ Yorùbá

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti bu ẹnu atẹ lu bi ajọ àwọn ìmáàmù ati Alfa se kéde Ustaz Abdul- Lateef Adekilekun gẹ́gẹ́ bí Waziri tuntun fún ilẹ̀ Yoruba.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori oye tuntun naa, Ọba Akanbi ni oun nikan loun lasẹ lati fi Waziri jẹ, nitori ọba lo ma n fi Waziri jẹ, kii se oye ti awọn ajọ̀ musulumi tabi alfa lee fi jẹ.

Oluwo ti Ilu Iwo ni, o gbọdọ ye awọn ọmọ ilẹ Yoruba pe oye ọba ni oye naa, nitori naa ni oun se yan Waziri Yaquob Abdul-Baki Mohammed, lati ọdun 2017.

O fikun wi pe, gbogbo ibi ti wọn ti n yan Waziri, ọba lo n yan. O ni awọn imaamu yan Waziri Mumini ni, eyi to yato si ti oun.

Oluwo ti Iwo

Oríṣun àwòrán, Instagram/Oluwo of Iwoland

Oluwo ni gẹgẹ bi ọba to ba lori oun gbogbo, ti kosi jẹ baalẹ ri, ni oun se gbagbọ wi pe ẹtanu ni awọn alfa fi yan Waziri ti won.

Ti a ko ba gbagbe, ajọ awọn imamu ti kede wi pe Ustaz Abdul- Lateef Adekilekun gẹgẹ bi Waziri tuntun ti ilẹ Yoruba.

Àwọn ìmámù ilẹ̀ Yoruba kọ ọ̀rọ̀ sí Oluwo lẹ́nu, wọ́n yan Waziri tuntun

Saaju ni ajọ imaamu ni ilẹ Yoruba ti tako Oluwo ti Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi lori yiyan ẹni ti yoo jẹ oye Waziri ti ilẹ Yoruba, ti wọn si yan Ustaz Abdul- Lateef Adekilekun gẹgẹ bi Waziri tuntun.

Aarẹ Ajọ imaamu ati awọn Alfa ni iwo-oorun orilẹede Naijiria, Edo ati ipinlẹ Delta, Sheikh Jamiu Bello lo ni ko tosi Ọba Akanbi lati gbe oye naa lo si ilu rẹ Iwo.

Oba AbdulRasheed Àkanbi ni oun fi oye naa pa owe ni.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Oluwo_of_Iwoland

Àkọlé àwòrán, Àjọ àwọn ìmámù ní ti kéde Onimọ̀ Ustaz Abdul- Lateef Adekilekun gẹ́gẹ́ bí Waziri tuntun ti ilẹ̀ Yoruba.

Sheikh Bello ni ẹni tuntun ti wọn yan naa jẹ akẹẹkọ gboye ninu ẹsin musulumi, ti o si tun jẹ akowe, onitan ati ẹni ti n saanu.

Ti a ko ba gbagbe, ọdun 2018 ni Oluwo bura pe oun yoo yan Yaquob Abdul-Baki Mohammed gẹgẹ bi Waziri ti ilẹ Yoruba.