Ẹ wo bi ìjà Portable àti Carter Efe ṣe lọ nílùú Eko

Portable wọ ibọwọ ẹṣẹ kikan, Carter Efe gbe ọwọ rẹ mejeeji soke o si so igbanu mọ idi

Oríṣun àwòrán, Portable/Carter Efe/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adẹrinpoṣonu to maa n ṣe sikiiti lori itakun ayelujara, Carter Efe, lu gbajugbaja akọrin takasufee, Habeeb Badmus ti ọpọ mọ si Portble ni alubami nigba tawọn mejeeji fija pẹta lalẹ ọjọ Ẹti niluu Eko.

Ni ṣe ni Efe rọ ojo ẹṣẹ le Portable lori ni gbọngan Balmoral Hall to wa ni ile itura Federal Palace nibi ti ija ọhun ti waye ni Victoria Island.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ami ayo awọn akẹṣẹ mejeeji ṣe sọ, awọn adajọ mẹtẹẹta lo sọ pe Efe lo jawe olubori ni gbogbo ipele ija naa.

Ami ayo 30-27 lawọn adajọ naa sọ pe Efe fi la Portable mọlẹ ninu ija ọhun.

Ṣaaju ni Portable ti gbegba oroke ninu ija to ja pẹlu oṣere Nollywood, Charles Okocha lọdun 2023 ati pẹlu akọrin Speed Darlinghton lọdun 2025.

Ṣugbọn ẹkọ ko ṣoju mumu fun Ọmọ Ọlalọmi nigba to koju Efe, ẹni to lu u laluki bi aṣọ ofi.

Ki ija naa to waye ni Portable t n leri wi pe oun yoo lu Efe lalubami tawọn ba koju ara awọn.

Portable ni Okocha ati Darlinghton toun ti lu sẹyin tobi ju Efe lọ, nitori naa, oun yoo fiya jẹ ẹ.

Amọ, esi ti Efe fun Portable ni pe iṣẹ kan ṣoṣo loun maa gba a to fi maa wo lulẹ.

''Ni ipele kẹta ni Efe bẹrẹ sii rọjo ẹṣẹ le Portbale lori''

Nigba ti ija ọhun bẹrẹ, Portable lo kọkọ bẹrẹ si ni ju ẹṣẹ si Efe, amọ, Efe n ṣọ ọ ko si jẹ ki ẹṣẹ rẹ Portble ba oun.

Portable tẹsiwaju ni ipele keji ija ọhun, amọ, Efe tun fẹsẹ mulẹ daadaa sii bi o ti n ṣọ Portbale.

Nigba to di ipele kẹta ni Efe bẹrẹ sii rọjo ẹṣẹ le Portbale lori ti o si bori Ọmọ Ọlalomi ninu ija naa.

Bayii ni Efe ṣe fẹyin Portble gbalẹ ti Ọmọ Olalomi si fidirẹmi fun igba akọkọ.

Ninu ọrọ rẹ, ọga agba Balmoral Group Promotions, Ezekiel Adamu, sọ pe awọn ṣe agbatẹru ija naa lati le jẹ kawọn eeyan mọ iru ẹbun tawọn abẹṣẹkubiojo naa ni.