Xenophobia: Àwọn ọmọ South Africa ní àwọn kò rí ìṣẹ́ ṣe, kí àjèjì máa lọ

Àkọlé fídíò, Xenophobia: Àwọn ọmọ South Africa ní àwọn kò rí ìṣẹ́ ṣe, kí àjèjì máa lọ

Ikọ iroyin BBC se abẹwo si orilẹede South Africa lati mọ bi ọwọja ikọlu awọn ọmọ onilu si awọn ajeji se gbalẹ to ati ohun to sokunfa rẹ.

Ninu iwadi BBC, a ri daju pe ọpọ ọmọ ilẹ Afirika lo faragba pupọ ninu ikọlu naa, ọpọ ile itaja lo jona, ọpọ mọto lo di eeru, ti aimọye ontaja si wọ gbese.

Abdallah Salajee, tii se ọmọ orilẹede South Africa gangan ti wọn dana sun ibudo to ti n ta mọto, fi itara sọrọ pe ko si idi to fi yẹ ki awa alawọ dudu maa kọju oro si ara wa bii eyi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe lootọ ni awọn eeyan oun n doju ikọlu wọn kọ ọpọ ajeji amọ sibẹ, awọn to jẹ ọmọ onilu bii ti oun naa n fara gba ninu rẹ.

Kamrul Hazzan tii se ọmọ orilẹede Bangladesh ni osu mẹta si mẹfa ni irufẹ ikọlu yii maa n waye, ti awọn ọmọ onilu yoo si wa ba ibudo itaja oun jẹ, bẹẹ ni ijọba ko gbe igbesẹ kankan, bi oun ba si ri iranwọ lọdọ ijọba, oun setan lati pada si orilẹede oun.

Ẹ wo fidio yii, kẹ fori ri ọpọ ofo ati adanu to waye lorilẹede South Africa nitori ikọlu awọn ọmọ onilu sawọn ajeji.