Nigeria models: Ẹ má bóra mọ́, ọmọ dúdú dùn lọ́mọbìnrin
Mo fẹran bi Adẹda ṣe da mi -Arinrin oge
Idowu Olutosin, onidiri arinrin oge to jẹ ọkan lara awọn to ṣagbekalẹ eto Ẹwatomi ba BBC Yoruba sọrọ nipa ẹwa obinrin.
O ni asiko ti to ki awọn adumaadan, ibadiaran, eyinfunjowo, aguntaṣọọlo obinrin Naijiria maa gbe ara wọn larugẹ.
O ni ko si ohun ti ẹni pupa le da lara ti ẹni dudu naa ko le fi yangan.
Yetunde Barnabas ọkan ninu awọn arinrin oge naa ni ko si nkan to le ba oun ninu jẹ lori bi Aṣẹda ṣe da aawọ ara oun.
O gba awọn neiyan ni imọran lati ni itẹlọrun pẹlu irufẹ aawọ ti Olọrun fun wọn laye.
Ẹnilari Olabisi to jẹ aṣojuloge ni eto Ẹwatomi yii n ṣafiwe ẹni dudu ati ẹni pupa papọ pe ko si eyi ti ko rẹwa ninu awọn mejeeji.
Jẹ ki aawọ ara rẹ tẹ ọ lọrun.