Bayelsa, Kogi Election: APC ní yóò jáwe olúbori

Oríṣun àwòrán, @tinubu
Olóri ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni yóò fẹ̀yìn gbogbo ẹgb míràn janlẹ̀ nínú ìdìbò gómǹà ti yóò wáyé ni Bayelsa àti Kogi.
Lóri pe boya gomina Kogi Yahaya Bello ṣe dáradára ni ìpínlẹ̀ Kogi ni sáà tó n lò lọ yìí, Tinubu ni tí kò ba sí ìhà tó ń fapajánu, èyí tumọ si pe kò si ijọba àwa àrawa.
"O pọ́ndandan kí a tẹti si ariwo ọja nítori pe oniruuru eso ló wà nibẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà lo ṣe ri pé ẹka oniruuru ni o wa ninu ọja, sùgbọ́n ẹgbẹ́ oní ìgbalẹ̀ yóò sọ ara rẹ̀ dí òṣùṣù ọwọ̀ láti gbá gbogbo ìdọti àti ẹyin wá dànù èyi si ni à ó lò lati jáwe olú bori"








