Premier league: Ìjà orogún London, Arsenal ati Tottenham ranjú mọ ara wọn, ṣùgbọn iná ojú wọn kò ran tábà

Arsenal àti Tottenham ta ọ̀mì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Diẹ lo ku ki omi tẹyin wọ igbin Arsenal lẹnu loni nibi ifẹsẹwọnsẹ awọn ati orogun wọn ni ilu Londọn, iyẹn Tottenham.

Tottenham ko fi ojuure wo Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi wọn ṣe side iya fun Arsenal ni iṣẹju kẹwa ifẹsẹwọnsẹ naa lati ẹsẹ Eriksen.

Ogoji iṣẹju ni Harry Kane, balogun ikọ Tottenham ba tun gba ọkan si.

Amọṣa, ṣe awọn agba bọ wọn ni bi ẹṣin ba da ni aa tuu gun ni. Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ isinmi fun saa akọkọ ni Lacazette, atamatase Arsenal da ọka pada ninu rẹ.

Arsenal jẹwọ ọmọ ọkọ fun Tottenham ni abala ikeji ifẹsẹwọnsẹ naa ṣugbọn pẹlu gbogbo kirakita wọn, goolu kan ṣoṣo ti Aubameyang gba wọle nikan ni wọn ri dimu eyi to ko wọn yọ ninu itiju naa.

Ori lo ko Tottenham pẹlu yọ lọwọ ogun atẹyinja ṣugbọn ṣa wọn sun iya ta lagba niluu London di ọjọ mii, ọjọọ re.

Arsenal àti Tottenham ta ọ̀mì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ọrọ orogun adedigba ni ifẹsẹwọnsẹ laarin Arsenal ati Tottenham maa n jẹ nitori ifigagbaga awọn mejeeji lori mimọ tani alagbara ẹkun ariwa ilu London, eyi ti a ms si North London.

Ireti ọpọ lori ifẹsẹwọnsẹ naa ko kuku ja sofo nitori bi ajere lo ṣe gbona janjan ṣugbọn lẹyin o rẹyin.

Ninu awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa to maa n du ipo mẹrin akọkọ lori atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi, iyẹn Manchester city, Liverpool, Arsenal, Manchester United, Chelsea ati Tottenham, Manchester city pẹlu Liverpool nikan lo bori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn lopin ọsẹ yii, ọmi ni Manchester United ati Chelsea ta ninu ifẹsẹwọnsẹ tiwọn to waye lọjọ satide.