#UEFAawards: Van Dijk gbadé UEFA mọ́ Messi àti Ronaldo lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Twitter/UEFA
Adẹyinmu fun ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil Van Dijk lo gbami ẹyẹ agbabọọlu UEFA to pegede julọ ni saa bọọlu to lọ.
Van Dijk fẹyin Cristiano Ronaldo ti Juventus ati Lionel Messi ikọ Barcelona gba lẹ gba ami ẹyẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Van Dijk wa lara awọn agbabọọlu to pegede nigba ti Liverpool na Tottenham pẹlu ami ayo meji sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije UEFA Champions Laegue ti saa to lọ.
- Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield
- Ọwọ́ ba Ole! Crystal Palace pàkúta sí gaàrí Manchester United ní Old Trafford
- A padà san owó ìtanràn fáwọn ajínigbé kí wọ́n to fi àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sílẹ̀- Ẹbí
- N650,000 péré ni mò ń gbà gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù -Gomina Ọyọ
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Amẹ́rika dá akẹ́kọ̀ọ́ padá nítori Facebook
Agbabọọlu Van Dijk to jẹ ọmọ orilẹde Netherlands lo ti n fakọyọ lati to ti darapọ ikọ Liverpool lati Southampton loṣu kinni ọdun 2018 fun pọun marunlelaadọrin(£75m).
Agbabọọlu naa ki awọn akẹgbẹ rẹ atawọn ti wọn ran an lọwọ lati gbami ẹyẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
O ni ti ko ba si awọn akẹgbẹ oun, ko lee ṣeeṣe fun oun lati pegede gbami ẹyẹ naa mọ Messi ati Ronaldo lọwọ.
Ṣé Van Dijk lè borí Ronaldo àti Messi nínú ìdíje UEFA?
Loni ni igbimọ adari ere bọọlu alafẹsẹgba UEFA yoo kede ẹlẹsẹ ayo tọdun yii nilẹ Yuroopu.
Awọn akọni mẹta ni wọn jọ n du ami ẹyẹ yii: adiẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil Van Dijk, Cristiano Ronaldo ti Juventus ati Lionel Messi to n gba bọọlu fun Barcelona.

Oríṣun àwòrán, Reserved getty image
Luka Modric lo yọ lara Ronaldo ati Messi lati gba ami ẹyẹ Ballon d'Or lọdun to kọja.
Opo n lero pe o ṣeeṣe ki Van Dijk gbegba oroke mọ Messi ati Ronaldo lara lọdun yii.
Messi ati Ronaldo:
Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo ni wọn ti n gba ami ẹyẹ yii mọ ara wọn lọwọ lati ọdun bii mẹwaa sẹyin.
Lọdun 2011 ti wọn kọkọ yan ẹlẹsẹ ayo UEFA.
Ronaldo ti gbaa ni ẹẹmẹta iyẹn ọdun 2014, 2016 àti 2017.
Nigba ti Lionel Messi ti gba a lẹẹmeji lọdun 2011 ati 2015.
Ronaldo lo ran Juventus lọwọ ti wọn fi bori ni Seria A nigba ti Messsi ran Barcelona lọwọ lati gba Liga.
Wo bi awọn mejeeji ṣe fakọyọ lọdun to kója si:

Oríṣun àwòrán, "others
Laarin ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2018 si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2019 ni esi abajade ifakọyọ awọn mejeeji ti fihan.
Messi ti gba goolu mẹrinlelaadọta sáwọn nigba ti Ronaldo ti gba mejilọgbọn sawọn.
Ta ni Van Dihk ti oju wa lara rẹ yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Van Dijk ló ti jé akọni pataki ni Liverpool lati igba to ti kuro ni Southampton nibi ti wọn ti bori Champions League ni saa to lọ.
Bakan naa ni o ṣe iranwọ fun Manchester City lati gba Premier League.
Van Dijk ni agbabọọlu adiẹyin mu akọkọ ti wọn yoo maa wo boya o le gba ami ẹyẹ naa.
Van Dijk ti kopa ninu idije mọkandinlọgọta to si ti gba ọpọlọpọ goolu sawọn.
Oun tun ni ẹlẹsẹ ayo Liverpool ati agbabọọlu to tii pẹ ju lagbaye (4,465).

Oríṣun àwòrán, @others
Ilu Monarco lorilẹ-ede Faranse ni ikede ẹlẹsẹ ayo naa yoo ti waye.












