Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ òfin ABU tí wọ́n jígbé lọnà Kaduna-Abuja ti gba ìdáǹdè -Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn mẹtẹẹta ti ri idande wọn gba -Ileeṣẹ ọlọpaa.
Lẹyin ti awọn agbofinro fi si ta pe wọn doola ẹmi awọn akẹkọọ ABU mẹta ti awọn ajinigbe ji gbe lọna Kaduna ni iroyin jade pe irọ ni pé awọn ọlọpaa lo kan kede riri wọn ni.
Sadiq Ango, ọkan lara mọlẹbi wọn ṣalaye pe niṣe ni awọn mọlẹbi mẹtẹẹta pawọpọ lati da owo san owo itanran ki awọn oniṣẹ ibi naa to fi wọn silẹ.
O fi soju opo twitter rẹ pe gbogbo owo itanran ti wọn beere ni awọn san.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa ni Bashir Ahmad to jẹ oluranlọwọ fun aarẹ Buhari lori eto iroyin igblode naa fi sita pe ẹbi awọn ti ọrọ kan ti fidiẹ mulẹ pe wọn san owo itanran ni.
O ni oun tọrọ aforijin lati kọkọ gbe gbogbo oriyin fun awọn agbofinro Naijiria tẹlẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ki lo ti ṣẹlẹ tẹlẹ?
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna ti kede itusilẹ awọn akẹkọọ Fasiti Ahmadu Bello ni Zaria mẹta ti awọn ajinigbe jigbe lọjọ Iṣẹgun loju ọna marose Kaduna si Abuja.
Alukoro ọlọpaa, DSP Yakubu Sabo lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC.
O sọ pe awọn doola ẹmi awọn akẹkọọ wọnyi ti wọn si ti darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn.
Yakubu ṣalaye pe awọn tun doola ẹmi awọn eeyan mẹta miran ti wọn jigbe loju ọna naa ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ.
O fi kun un pe iwadii ṣi n lọ lati doola awọn eeyan to ku ati pe awọn n ṣapa lati mu awọn afurasi naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi alaye ti awọn ọlọpaa ṣe, iṣẹlẹ naa waye nigba ti awọn ajinigbe to wọ aṣọ ologun ji awọn ero inu ọkọ gbe lẹba abule Masari loju ọna Kaduna si Abuja ti wọn si ṣina fawọn ọkọ to wa ni ọna naa.
Wọn ji eeyan mẹfa gbe lọjọ Aje ti iṣẹlẹ naa waye.
Adari awọn to n ṣe eto awọn akẹkọọ ni Fasiti ABU Ọjọgbọn Yahaya Bambale fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC to si ni lootọ lawọn ajinigbe gbe akẹkọ mta ṣugbọn awọn agbofinro ti toju bọ ọrọ naa.












