Ilé Aṣòfin Eko: A fẹ́ mọ̀ bí Ambode ṣé nà ₦45b tó fi ra BRT

Akinwunmi Ambode n sọkalẹ ninu ọkọ BRT

Oríṣun àwòrán, Lagos Eye News

Igbimọ ti Ile Aṣofin ipinlẹ Eko gbe kalẹ lati ṣe iwadii lori bi Gomina ana nipinlẹ naa, Akinwunmi Ambode, ṣe na owo lati ra ọkọ akero BRT, ti wi pe, iwadii wọn kii ṣe lati dẹyẹ si gomina ana ọhun.

Fatai Mojeed, ẹni tii ṣe alaga igbimọ naa sọ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC pe, iwadii ti wọn n ṣe nipa bi Ambode ṣe na owo lori awọn ọkọ akero naa jẹ ojuṣe awọn aṣofin ipinlẹ Eko.

O ṣọ ninu ọrọ rẹ pe, ko si ẹtanu kankan ti wón ni si Ambọde, ẹni ti o ṣe ijọba ni ipinlẹ Eko laarin ọdun 2015 si 2019.

Fatai wi pe, "Kii ṣe pe awọn aṣofin n dẹyẹ si Ambode, sugbọn ojuṣe wa la n ṣe gẹgẹ aṣofin."

"Ambode, wá jẹ́jọ́ lórí ọkọ̀ BRT 5000 tó o ₦45b rà, àmọ́ 820 péré ló kó wá"

Ile aṣofin ipinlẹ Eko ti ṣe agbekalẹ igbimọ kan lati ṣe iwadii bi Gomina ana nipinlẹ naa, Akinwumi Ambode ṣe na biliọnu marundinlaadọta naira to fi ra ọkọ akero .

Lọjọ Iṣẹgun ni ile panupọ pe, o di dandan lati wadi kulẹ kulẹ nipa bo ṣe jẹ ọkọ okolelẹgbẹrin (820) ni ijọba Ambode ra dipo ẹgbẹrun marun un ọkọ̀ (5000) ti o daba.

Bakan naa ni wọn ni ile nigba naa, lodi si rira awọn ọkọ akero yii.

Aṣofin Gbolahan Yishawu, to n ṣoju ẹkun idibo Eti Osa keji lo daba yii, to si sọ pe ijọba daba lati na biliọnu mẹtadinlogun naira (₦17b) lati ra awọn ọkọ wọn yii, ninu aba isunna ọdun 2017 ṣugbọn ile ko buwọlu.

Ọkọ akero BRT

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria

O ni ''ninu aba isunna ọdun 2018 ati ti 2019 ijọba daba lati na biliọnu mẹrinlelogun ati biliọnu meje naira lori awọn ọkọ wọn yii, amọ ile ko fọwọ si nina owo yi''

Yishau tẹsiwaju pe ''tohun ti bẹẹ, ijọba gbe ọkọ okoolelẹgbẹrin (820) wọle lati oke okun ni biliọnu meje naira, to si jẹ pe ọkọ okoolelẹẹdẹgbẹta (520) ninu awọn ọkọ yii ṣi wa ni ibudoko ọkọ oju omi.'

Eyi to tumọ̀ si pe ọọdunrun ọkọ BRT pere lo fi owo naa ko wọ ilu, tawọn eeyan fi oju ri.

Ambode
Àkọlé àwòrán, Nkan ko fẹ ṣẹnu re fun Gomina ana Akinwumi Ambode lati igba to ti kuro lori alefa nipinlẹ Eko

Lẹnu lọọlọ yii, Gomina tẹlẹri Ambode ti n koju awọn ipenija lọdọ awọn agbofinro paapaa julọ, lọdọ ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra EFCC to yabo ile rẹ ni Epe.

Ki Ambode to kuro lori oye ni oun ati ile aṣofin ipinlẹ Eko ko ti gbọ ara wọn ye daadaa, ti iroyin si kan nigba naa pe wọn fẹ yẹ aga ni idi rẹ.

Ni nnkan bi ọsẹ mẹta sẹyin ni adajọ agba kan ni ki wọn gbẹsẹ le akoto owo ti biliọnu mẹsan naira wa ninu rẹ, eleyi ti wọn fura si pe o ni ohun ṣe pẹlu Ambode.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ambode ti tako ọrọ yi pe oun ko ni nkankan ṣe pẹlu akoto naa tabi owo to wa ninu rẹ.

Asofin Fatai Mojeed to n ṣoju Ibeju Lekki ni ile aṣofin Eko ni ko dari igbimọ ti yoo ṣe iwadii yi ti wọn si ni ko jabọ fun ile bi ọrọ ba ti ṣe ri.

Bakan naa ni olori ile paṣẹ ki wọn fiwe pe adari ile iṣẹ LAMATA to n ṣe eto awọn ọkọ akero to fi mọ awọn miran lati wa wi tẹnu wọn naa.