Akinwunmi Ambode: Ìsúná 2019 fi N1trn kéré sí ti 2018

Gomina Ambode

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Adarí Ilé Asòfin, Modashiru Obasa ní inú òun dùn báyìí pé Gomina Ambode gbé àbá ìsúná 2019 sílẹ̀.

Gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Akinwunmi Ambode ti gbe eto isuna to to ọtalelẹgbẹrin o din mẹjọ biliọnu Naira (N852.13bn) siwaju Ile Asofin ipinlẹ naa.

Iroyin ni eto isuna ti ọdun yii kere ju ti ọdun to kọja lọ pẹlu triliọnu Naira kan (N1.046trn).

Ambode sọ wi pe, awọn pese eto isuna naa lati le koju awọn ise akanse to niise pẹlu awọn opopona ti wọn n se, bii Oshodi si Murtala Mohammed International Airport Road ni agbeegbe Agege.

Gomina Akinwnumi Ambode
Àkọlé àwòrán, Ambode

Adari Ile Asofin, Modashiru Obasa ni inu oun dun bayii si bi Gomina Ambode gbe aba isuna 2019 silẹ.

Laipẹ yii ni Ile Igbimọ Asofin ipinlẹ naa gbe igbesẹ lati yọ Gomina Ambode kuro nipo, amọ Adari Ẹgbẹ Oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo pẹẹtu saawọ awọn mejeeji.