Nollywood: Funmilayo Ogunsola mí kanlẹ̀ lásìkò àìsàn ráńpẹ́

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ilumọọka osere tiata kan, Funmilayo Ogunsola, ti gbogbo eniyan mọ si Mama Ijẹwuru, ti papoda lẹyin aisan ranpẹ ni ile rẹ ni Ibadan.
Ijẹwuru ni iyawo kẹrin fun gbajugbaja osere tiata kan to ti di oloogbe, Ishola Ogunsola, to jẹ ọkan gboogi ninu awọn oludasilẹ ẹgbẹ awọn oni tiata lorilẹede Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Molebi arabinrin naa, Adebisi Ogunsola lo fi isẹlẹ naa lede loju opo ikansiraẹni Facebook rẹ.
Ọpọlọpọ eniyan mọ obinrin naa bii ẹni to ma n se bi odi ninu ere tiata.
Awọn akẹẹgbẹ rẹ ni Jimoh Alihu, Charles Olumo, ati Afolabi Afolayan (Jagua) to ti papoda.









