Nigeria election 2019: Ipa tí àwọn bàbá ìsàlẹ̀ ń kó nínú ètò òṣèlú rèé

Godswill Akpabio
Àkọlé àwòrán, Baba isalẹ oṣelu Naijiria

Baba isalẹ ninu eto oṣelu orilẹ-ede Naijiria kii saaba dije fun ipo oṣelu fun rara wọn.

Ọpọ gbagbọ pe awọn gan an ni wọn maa n ṣagbatẹru awọn ti yoo wọle ibo ati wọn ti yoo kùnà nigba idibo.

Bi idibo gbogboogbo ọdun 2019 ti n kan lẹkun, awọn baba isalẹ yii ni wọn maa gbowo kalẹ lati ṣatilẹyin fun awọn oludije idibo ti wọn ba fa kalẹ.

Awọn eeyan tun gbagbọ pe awọn ti wọn ba fa kalẹ yii kii saba jẹ agbaọjẹ oloṣelu, ṣugbọn wọn maa n di ipo oṣelu mu lati sanjọ fawọn baba isalẹ to ba fa wọn kalẹ to ba ya.

Àkọlé fídíò, 'A ni òfin púpọ̀ ní Naijiria ṣùgbọ́n a kò bọ́wọ́ fún un ni'

Eleyi ni olukọ agba ni ẹka eto ẹkọ oṣelu nile iwe giga fasiti ilu Eko Ọmọwe Dele Ashiru n pe ni baba isalẹ ninu oṣelu.

O sọ ninu ọrọ rẹ pe ko si ohun ti awọn baba isalẹ yii ko le ṣe lati ri i pe ẹni ti wọn fa kalẹ wọle.

O fikun ọrọ rẹ pe lọpọ igba awọn baba isalẹ yii maa n jẹ oloṣelu to di ipo kan tabi omiran mu.

Ni apa gusu orilẹ-ede Naijiria ni nipinlẹ Akwa Ibom, ọpọ lo gbagbọ pe Ọgbẹni Godswill Akpbio ni baba isalẹ oṣelu ipinlẹ naa, Akpabio jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.

Eto oṣelu Akwa Ibom
Àkọlé àwòrán, ọrọ oṣelu Naijiria

Gomina Ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ ri Akpabio si tun lẹnu ninu eto oselu ipinlẹ naa bo tilẹ jẹ pe o jẹ sẹnẹtọ lọwọlọwọ.

Bi Akpabio ṣe fi ẹgbẹ osẹlu PDP silẹ darapọ mọ APC laipẹ yii tiẹ jẹki ọpọ ro pe APC le jawe olubori ninu eto idibo to n bọ nipinlẹ naa fun igba akọkọ lati igba ti Naijiria ti pada si ijọbo awa ara wa.

Ẹwẹ, sẹnẹtọ Akpabio fun ra rẹ sọ pe oun kii ṣe baba isalẹ fun ẹnikankan ninu eto oṣelu Ipinlẹ Akwa Ibom.

Ṣugbọn o ni igba to dabi ẹni pe oun wuwa bi baba isalẹ oṣelu ni ọdun 2015 ti oun fa gomina Ipinlẹ Akwa Ibom kalẹ.

Ọkan lara awọn alatilẹyin Gomina Ipinlẹ Akwa Ibom
Àkọlé àwòrán, Baba isalẹ ninu eto oṣelu
Àkọlé fídíò, Ademọla Ogunbanjo: A nílò bàbá ìsàlẹ̀ nínú òsèlú

Amugbalẹgbẹ Akpabio tẹlẹ ri tiẹ ṣalaye pe o ṣe iranwọ owo fun oun nigba ti oun ṣe igbeyawo ati ọjọ ibi ogoji ọdun. O ni oun lo jẹ ki oun gberi ninu eto oṣelu.

Eto oṣelu nipinlẹ Akwa Ibom
Àkọlé àwòrán, Baba isalẹ ninu oṣelu

Eto oṣelu apa ariwa Naijiria

Eto oṣelu ni ipinlẹ Kano to jẹ pe awọn ẹlẹsin musulumi lo pọ nibẹ nii ṣe pẹlu baba isalẹ eto oṣelu ipinlẹ naa.

Eto oṣelu lapa Ariwa Naijiria
Àkọlé àwòrán, Ọrọ osẹlu Ipinlẹ kano

Ipinlẹ Kano lo si keji ninu awọn ipinlẹ to ni awọn oludibo ju lorilẹede Naijiria, eleyi to jẹ ko ṣe pataki fun ẹgbẹ oṣelu mejeeji APC ati PDP lati jawe olubori ninu ibo to n bọ.

Gomina ipinlẹ kano tẹlẹ, Rabiu Kwankwaso ni atilẹyin ọpọ eeyan ni ipinlẹ naa, eleyi ṣẹlẹ lẹyin ti ṣe eto ẹkọ ọfẹ nigba ti o ṣe ijọba gẹgẹ bi gomina.

Kwankwaso tiẹ ni ẹka osẹlu rẹ ti wọn n pe ni Kwankwasiyya Movement nipinlẹ Kano.

Kwankwaso n ṣatilẹyin fun Abba kabiru Yusuf to n dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Àkọlé fídíò, BBC Gov Debates: Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn olùdíje yóò ṣe
Rabiu Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rabiu Kwankwaso

Àkọlé àwòrán, Oṣelu ipinlẹ Knao

Ṣugbọn ohun to saaba maa n sẹlẹ ni pe awọn baba isalẹ ati awọn ti wọn ba fa kalẹ saaba maa n ni ede aiyede.

Ọrọ baba isalẹ oṣelu
Àkọlé àwòrán, Ọrọ oṣelu Naijiria

Eto idibo to n bọ yoo fihan bo ya awọn ẹni ti Akpabio ati Kwankwaso fa kalẹ yoo wọle tabi wọn yoo kuna.

Àkọlé fídíò, Falana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria