Emiliano Sala: Wón ti rí bààlú agbábọ́ọ́lù tó pòórá nínú òkun

Emiliano Sala ati David Ibbotson

Oríṣun àwòrán, Getty Images/David Ibbotson

Àkọlé àwòrán, Emiliano Sala (apá òsì) wà nínú ọkọ́ òfúrufú náà tí David Ibbotson wà

Eyi to ku ninu ọkọ̀ ofurufu to gbe agbabọọlu Cardiff City, Emiliano Sala to poora ni wọn ti ri ninu okun to wa laarin Ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ-ede Faranse.

Baalu naa to jẹ Piper Malibu N264DB ni o sọnu ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu kini nigba to n lọ lati ilu Nantes ni Faranselọ Cardiff.

Agbabọọlu ọmọ Argentina naa ati arakunrin to tu'kọ naa, David Ibbotson nikan lo wa ninu rẹ.

Àwọn oluwadii ti ni awọn yoo ran ọkọ to n ṣe iwadii abẹ omi lọ sibi ti wọn ti ri ajaku baalu naa ni ọjọ Aje.

David Mearns, to n dari awọn to n wa ọkọ naa lati ọjọ to sọnu ni agbegbe Guernsey ni wọn ti ri ajaku ọkọ naa labẹ omi ni ọjọ Aiku.

Ileeṣẹ to n ṣe iwadii ijamba ọkọ ofururu ti wa ni ibẹ bayii lati gbe ajaku baalu naa jade.

Aworan to fi ibi ti baalu Sala ti poora ree lọna Nantes si Cardiff

Oríṣun àwòrán, BBC

Àkọlé àwòrán, Agbabọọlu naa di awati lẹyin to buwọlu adehun Cardiff
Àkọlé fídíò, Ọ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé
Àkọlé fídíò, Ademọla Ogunbanjo: A nílò bàbá ìsàlẹ̀ nínú òsèlú

Ọpọlọpọ ọrọ ibanikẹdun lo wọle lo ti n wọle lati igba ti ọkọ naa poora.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ Cardiff gba ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ lati igba ti baalu Sala ti poora ni ọjọ Abamẹta.

Ọkọ oju omi Geo Ocean III to n wa baalu naa

Oríṣun àwòrán, Rich Watson / Geoxyz

Àkọlé àwòrán, Ọkọ oju omi Geo Ocean III ko kuro ni agbegbe ti wọn ti ri ajaku ọkọ naa ni Guernsey

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ si: