2019 elections: INEC ní káàdì ìdìbò 15,000 táwọn ọ̀daran jó ní iléeṣẹ́ INEC kò leè dáwọ́ ìdìbò dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eeyan kan ti dana sun ọpọlọpọ kaadi idibo to to ẹgbẹrun marundinlogun ni iye nileeṣẹ ajọ INEC to wa ni ipinlẹ Abia.
Gẹgẹ bii awọn alaṣẹ ajọ eleto idibo INEC lagbegbe naa ṣe sọ, awọn kaadi idibo ti wọn dana sun naa ni awọn ti o ku ti awọn oludibo to ni wọn ko tii wa gba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iṣẹlẹ yii waye ni owurọ ọjọ aiku.
Bakan naa lawọn leṣebi-leṣeka ẹda naa tun dana sun iwe orukọ awọn oludibo nibẹ.

Oríṣun àwòrán, INEC
Kọmiṣọna feto idibo nipinlẹ Abia, Joseph Iloh fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ aiku. O ni oju ferese lawọn omiṣẹ ibi naa gba wọle.
O ni lootọ awọn eeyan yii jo iwe orukọ ati kaadi idibo awọn oludibo nibẹ ṣugbọn ojulowo iwe orukọ oludibo wa ni olu ileeṣẹ ajọ naa to wa ni ilu Umuahia.
Nibayii naa, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn to wa nidi iṣẹ ibi naa.













