#BBCNigeria2019:Àkójọpọ̀ àwòrán láti ìpàdé ìtagbangba pẹ̀lú àwọn olùdije ní Ọyọ

Eyi ni akojọpọ awọn aworan to lamilaaka nibi ipade itagbangba ni Ọyọ:

Oyo
Àkọlé àwòrán, Ipade itagbangba ti BBC New Yoruba fun awọn oludije si ipo gomina ni ipinlẹ Ọyo waye ni Ọjo Kini, Osu Keji, ọdun 2019 saaju idibo gbogboogbo.
Oyo
Àkọlé àwòrán, Gbogbo awọn oludije naa lo pinnu lati san 30,000 gẹgẹ bi owo osu osisẹ to kere julọ.
Oyo
Àkọlé àwòrán, Bolanle Sarumi to n dije dupo gomina ni gbogbo awon ọmọ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju marun lọ yoo gba eto ilera ofe.
Ọyọ
Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló ń ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Ọyọ
Oyo
Àkọlé àwòrán, Lori ijọba ibilẹ, gbogbo awọn oludije ni wọn ni awọn yoo da idaduro ijọba ibilẹ pada
Oyo
Àkọlé àwòrán, Gbogbo awọn oludije to yọju lo wu awọn eniyan lori pẹlu gbogbo alakalẹ aato wọn lọlọkan o jọkan ti wọn ni awọn yoo gbe ṣe bi awọn ba di gomina ipinlẹ Ọyọ.
Oyo
Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan ara ipinlẹ Ọyo farabale lati gbogbo nkan ti awon oludije ni fun won.
Oyo
Àkọlé àwòrán, Adebayo Adelabu sọ pe oun yoo gbe iṣe agbe larugẹ. O ni oun yoo koju si Oke Ogun fun nnkan ọgbin jijẹ ati tita.
Oyo
Àkọlé àwòrán, Akala sọ pé oun ko nii maa gbe iṣe ti awọn ara Ọyọ le ṣe fun awọn ara ita.
Oyo
Àkọlé àwòrán, Sarumi ni awọn akanda ẹda ti n dojukọ idẹyẹsi l'awọn bank ati bẹẹbẹ. O ni oun yoo fopin si idẹyẹsi. Ati pe awon ileewe ti gbogbo ọmọ ba n lọ ni awọn akanda naa yoo maa lo
Oyo
Àkọlé àwòrán, Awọn oludije dupẹ fun awon eeyan ti won jade wa. Ijoba tiwantiwa, ijoba araalu, ti yoo pa araalu lẹrin ni awọn yoo ṣe.