'Àṣìṣe ló mú mi fi ọmọ odó pa ọ̀rẹ́bìnrìn mi'

Oríṣun àwòrán, irt
Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun yoo gbe Edeh Tochukwu, ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ti wọn fura si pe o pa ọrẹbinrin rẹ, Ijeoma Phyliss, lọ si ile ẹjọ gia ijọba apapọ nilu Abuja.
Ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ IRT mu Ọgbẹni Edeh Tochukwu Christian, fun ẹsun pe o pa ọrẹbinrin rẹ, ẹni dun mọkanlelọgbọn, ni agbegbe Lugbe niluu Abuja.
Ninu atẹjade ti ajọ IRT fi sita nilu Abuja sọ pe Tochukwu salọ, lẹyin to pa arabinrin Ijeoma tan, to si tun gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, awọn foonu ati awọn dukia rẹ miran salọ.
“Ọwọ ọlọpaa IRS tẹ afurasi naa niluu Port Harcourt, nipinlẹ rivers, lọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, lẹyin to salọ kuro nibi to pa oloogbe si, to si lọ n gbe pẹlu obinrin mii, to jẹ ololufẹ rẹ tuntun.”
Lasiko ti wọn fi oju rẹ han funa araye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022, afurasi naa sọ fun awọn akọroyin niluu Abuja pe ọmọ odó ni oun fi gba lẹyin ori “nitori pe o ma n fi iya jẹ oun”.
O ni ọpọ igba ni awọn ma n ja, eyi ti awọn n gbiyanju lati yanju, ko to o di pe ija bẹrẹ.
Tochukwu sọ fun BBC pe oun ko mọọmọ pa ọrẹbinrin oun, pe aṣiṣe ni.
O ni ori ayelujara Facebook ni oun ti pade Ijeoma, lọdun 2020, ti wọn si di ọrẹ, amọ oun ko ni erongba lati fẹ ẹ.
“Asiko ti a mọ ara wa, sunmọ ọjọ ibi rẹ. O pe mi lati wa ba a ṣe ayẹyẹ, nitori pe ko ni ọrẹ pupọ. Ọjọ naa si ni ọjọ akọkọ ti mo lọ si ile rẹ, lẹyin ti a ṣe faaji tan.
“O sọ gbogbo iriri rẹ lọwọ awọn ọkunrin to ti fẹ sẹyin fun mi, ati bo ṣe jẹ pe ko tii fẹ ọkunrin kankan lati bi ọdun mẹjọ sẹyin. “
O ni bakan naa ni oloogbe Ijeoma tun sọ fun oun pe oun nilo ololufẹ ati ọmọ ni kiakia.
“Lẹyin ọsẹ meji to sọ awọn nkan yii fun mi, mo pinnu lati bẹrẹ irinajo ifẹ pẹlu rẹ, nitori pe eeyan daada ni, o si n tọju mi.”
“Aṣọ ati awọn nkan aṣaraloge to le mu mi rẹwa lo ma n ra fun mi, nitori pe oniṣowo aṣọ ati awọn ẹṣọ ara ni, amọ kii fun mi ni owo.”
Ọgbẹni Tochukwu sọ pe lẹyin oṣu diẹ ti wọn bẹrẹ irinajo ifẹ, ni arabinrin Ijeoma bẹrẹ si ni yipada, o n fura si mi, o si tun n lo iwa ipa pẹlu oun.
“Mo kọkọ lero pe nitori awọn iriri to ti ni pẹlu ọkunrin tẹlẹ lo fa awọn iwa naa, eyi to mu ki n mu lọ si ọdọ awọn ẹbí mi lati fihan pe oun ni iyawo ti mo fẹ ẹ fẹ. Amọ, igbesẹ mi ko mu adinku ba awọn iwa to n hu si mi.”
Tochukwu sọ pe ẹgbẹrun marundinlọgọrin ni owo oṣu oun nibi to ti n ṣe iṣẹ olukọ.
Wahala nla bẹrẹ ninu irinajo ifẹ wọn, nigba to ni oloogbe Ijeoma n beere fun ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira loṣooṣu lati ma a fi kun owo ounjẹ ati awọn nkan mii nilu ile Ijeoma ti wọn jọ n gbe.
“Nigba ti mi o ri owo naa ko silẹ, o sọ mi di iyawo ninu ile. Emi ni mo n tun ile ṣe bi ọmọ ọdọ, o n ri mi fin, o si tun n lo mi ni ilokulo ninu ile.”
Arakunrin naa sọ pe awọn ti tu irinajo ifẹ ka, ko to o di ọjọ to pa Ijeoma.
O ni arabinrin naa lo ranṣẹ pe oun lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, to si ni ki oun da ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Highlander to ra fun oun pada niwọn igba ti oun sọ pe oun ko gbe nile oun mọ.
Ọrọ ọkọ ayọkẹlẹ naa lo fa ariyanjiyan laarin wọn ko to o di pe o fi ọmọ odo lu u lori.
O ni lẹyin ariyanjiyan, oun wọ yaara keji lati sun ninu ile naa, amọ ṣadeede ni oun ni irora ni ẹgbẹ́ oun lati oju orun, pẹlu nkan ti Ijeoma fi gba.
“Bi mo ṣe laju, lo n pariwo pe oun kii ṣe iru obinrin ti mo le yanjẹ, ninu ki n pa oun tabi ki oun pa mi.
“Kia, o ti ti ilẹkun inu ile pa, o si fi kọkọrọ pamọ. Ọpọ igba lo fi ọmọ odo naa lu mi, ko to o di pe mo ri i gba lọwọ rẹ.
“Ni nkan bi aago mẹta oru kọja iṣẹju marun-un, ti mo ri ọmọ odo naa gba ni mo fi gba lẹyin ori nitori bi inu ṣe bi mi.
O ni inu bo ṣe n sunkun, ni oun raaye gba ọna ẹyinkule jade, ti oun si gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ nitori ki awọn oṣiṣẹ alaabo agbegbe naa le jẹ ki oun jade.
“Bakan naa ni mo ko awọn foonu rẹ, ko ma ba a pe mi.”

Oríṣun àwòrán, irt
Awọn ẹbi oloogbe Ijeoma Phillis sọ pe ọjọ kẹrin ni alamojuto ile naa pe ẹgbọn Ijeoma lori foonu, pe awọn ko rii ko jade.
Eyi mu ki wọn o pe awọn ọlọpaa, to wa lati wọ inu naa nibi ti wọn ti ba oku rẹ ti wọn fi rọọgi bò, to si ti n rùn.
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa lori ayelujara Facebook rẹ, Arabinrin Ijeoma gba oye imọ ijinlẹ ninu Sociology ni Fasiti ilu Abuja.
Oniṣowo ni, to si ni awọn ile itaja siluu Abuja nibi to ti n ta aṣọ ati awọn nkan iṣaraloge mii.












