Ìjọba, ẹ má jẹ́ ká kú sí àkàtà àwọn ajínigbé o, ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ girama táwọn agbébọn jígbé pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ l'Ogbomoso ké gbàjarè

Oríṣun àwòrán, Hon Olamijuwonlo Alao Akala/Facebook
Ọga ile ẹkọ girama Community High School, Esinele ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbọmoso, Arabinrin Alamu F.R. ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ, Gomina Seyi Maiinde ipinlẹ Oyo atawọn ọmọ Naijiria lati doola oun atawọn akẹkọọ ile ẹkọ naa tawọn janduku agbebọn jigbe lọjọ Ẹti to kọja tii ṣe ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un yii.
Arabinrin Alamu sọ ninu fidio kan to wa lori itakun ayelujara pe ni nnkan bi ago mẹsan an aabọ owurọ ọjọ Ẹti to kọja lawọn agbebọn kan ṣekọlu si ile ẹkọ naa ni Esinele ti wọn si ji oun atawọn akẹkọọ kan gbe lọ.
Ọga ile ẹkọ naa tun fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa wa lara awọn tawọn agbebọn naa jigbe, gbogbo wọn si ti wa ninu igbo lati ọjọ Ẹti.
''Mo ṣe fidio yii lati beere fun iranwọ lọwọ gbogbo eeyan, bẹrẹ lati ọdọ ijọba apapọ Naijiria, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo, ajọ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN ati gbogbo eeyan.
Mo fẹ ki ẹ bawa yanju ọrọ yii ni itubi inubi ki a maa baa ku sibi,'' Arabinrin Alamu lo sọ bẹẹ.
Ọga ọlọpaa Naijiria ṣabẹwo si Oriire nibi tawọn agbebọn ti ji ọga ile ẹkọ atawọn akẹkọọ gbe lọ
Ẹwẹ, ọga ọlọpaa Naijiria, Tunji Disu, ti ṣabẹwo si ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso nibi tawọn agbebọn ti ji ọga ile ẹkọ, awọn oṣiṣẹ atawọn akẹkọọ lọ ni Esinele.
Ọga ọlọpaa fi aidunnu rẹ lori iṣẹlẹ naa, o si kẹdun pẹlu ẹbi awọn eeyan to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Disu kọwọọ rin pẹlu Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Ojo Adekimi, latari bi ijọba ibilẹ Oriire ṣe paala pẹlu ipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọna ọlọpaa to n ri si eto aabo awọn ile ẹkọ, CP Abayomi Shogunle, naa wa lara awọn to tẹle ọga ọlọpaa Naijiria lọ si ijọba ibilẹ Oriire.
Lasiko abẹwo ọhun ni Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Abimbola Ayodeji Olugbenga, jabọ fun ọga agba ọlọpaa Naijiria lori ibi ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ba iṣẹ iwadii de.
Ọga agba ọlọpaa wa sọ fun gbogbo awọn obi ati alagbatọ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ awọn ẹṣọ eleto aabo mii ti n ṣisẹ takun takun lori a ti doola awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ tawọn agbebọn jigbe lọ.
O ni gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin.
Ọga agba ọlọpaa to bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa ṣeleri pe alaafia yoo pada jọba lagbege ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Disu tun paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọlọpaa mii lọ si ijọba ibilẹ Oriire lati ṣawari ati lati doola awọn ti wọn jigbe ninu igbo.


























