Makinde ní ìjọba kò gbọdọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ètò ààbò, ṣe ìfilọ́lẹ̀ ikọ̀ tí yóò máa mójútó ìwà ọ̀daràn

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi makinde ti ṣe ifilọlẹ ikọ ti yoo maa mojuto iwa ipa iyẹn "Violent Crime Response Unit (VCRU) ti ijọba apapọ ṣẹṣẹ ṣagbedide rẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa.
Makinde gboriyin fun igbesẹ naa, bo ṣe ni ṣiṣe agbedide ikọ bẹẹ lasiko yii jẹ ohun to tọna paapaa bi iṣẹlẹ ijinigbe atawọn iwa ipa ṣe n pọ si ni ojoojumọ.
Nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ naa to waye lọjọ Abamẹta ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to w ani agbegbe Eleyele ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, ni ṣiṣe agbedide ikọ naa ṣafihan erongba ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ lati mu igbooro bae to aabo ni ipinlẹ Oyo.
Makinde ni ijiroro ti oun ni pẹlu Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo fi han pe ikọ naa ni akọkọ iru rẹ ni guusu ẹkun iwọ oorun Naijiria.
O ni iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni ijọba ibilẹ Oriire nibi ti wọn ti ji ọpọ awon ọmọde gbe jẹ ki siṣe idasilẹ ikọ naa ṣe pataki.
O fi kun pe iṣẹlẹ ijinigbe to waye naa ti mu ki awọn eeyan ipinlẹ Oyo wa ninu inu fu aya fun bayii atawọn ẹbi awọn ọmọ tawọn ajinigbe naa ṣekọlu si.
Gomina nMakinde tẹsiwaju pe ijọba ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo lojuna ati fidii ohun to ṣẹlẹ lori ikọlu naa mulẹ
Bakan naa lo ba awọn obi awọn ọmọ ti wọn padanu emi wọn kẹdun, to si gbadura ki Ọlọhun tẹ awọn ọmọ naa si afẹfẹ rere.
O ni eto aabo jẹ ohun ti ẹnikẹni ko gbọdọ fi ṣere rara bo ṣe ni iṣẹlẹ to waye naa ti ṣafihan inilo lati maa wa ni oju lalakan fi n ṣọri ni gbogbo igba.
O woye pe awujọ ti aabo rẹ ba peye ni idagbasoke ti maa n bae to ọrọ aje, idokoowo, inaju ati igbayegbadun awọn eeyan, ti awọn eeyan si maa ni itẹriba fawọn ohun to jẹ ti ijọba.
Gomina wa juwe ikọ VCRU bi awọn to poju owo, ti wọn si le tete ji giri si ojuṣe wọn lsti koju iwa ọdaran, ti wọn ko si ni fi igba kan bọ omiran ninu, ti wọn yoo si maa bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.
Bẹẹ naa lo tun jẹwọ atilẹyin ti n ṣe fawọn ẹṣọ aabo, to si ni awọn ko ni dawọ awọn atilẹyin bii ipesẹ nnkan irinsẹ atawọn ohun eelo mii ti wọn nilo lati fi ṣe ojuṣe wọn.
Makinde wa kan saara si ẹka naa, to si ni ohun gbagbọ pe wọn ti gbaradi lati bẹrẹ ojuṣe wọn.
O ni awọn yoo maa ṣe atilẹyin fawọn ẹṣọ aabo ni ipinlẹ Oyo pẹlu erongba pe wọn maa tẹsiwaju lati maa da aabo bo emi ati dukia awọn araalu ati ti ijọba.
O tẹmpẹlẹmọ pe ojuṣe aabo kii ṣe fun ẹnikankan rara, to si parọwa sawọn araalu ki wọn wa ni oju lalakan fi n ṣọri ki wọn si maa ṣe atilẹyin fawọn ẹṣọ aabo ni gbogbo igba.
Bakan naa lo tun gboriyin fun ọlọpaa Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fun iṣẹ naa bi o ṣe kede pe ajọṣepọ ijoba apapọ ati ijoba ipinlẹ ni.
Ṣaaju ni Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo, Abimbola Ayodeji Olugbenga sọ pe idasilẹ VCRU lo jẹ afojusun ọga agba ọlọpaa Naijiria lojuna ati mu ayipada ba awọn ikọ to n ṣiṣẹ ni ẹka naa tẹlẹ ri ki wọn ba a tun le maa ṣiṣẹ to poju owo.
O ni wọn ṣe agbedide ikọ naa lati tete maa mojuto iwa ọdaran to ba n waye lai tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ ati lai lugbadi ofin.
O ṣalaye pe gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn ko sinu ikọ naa ni wọn ti ṣe idanilẹkọọ to peye fun ti wọn si maa ṣe agbedide igbimo laipẹ ti yoo maa mojuto iṣẹ ti wọn ba n ṣe.


























