Àwọn ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa Ìjàpá Ogbomoso kó tó kú

Lẹ́yìn tí Ijapa to dagba ju nilẹ Afirika yii dagbere faye lẹni ọdun mejilelọọdunrun, ile iṣẹ BBC ṣewadii awọn nkan to laami laaka nipa rẹ.
Gẹgẹ bí awọn akọṣẹmọṣẹ atawọn onimọ nipa itọju ẹranko ṣe sọ ọ, aaringbugbun gbekede ti ijapa n lo laye ni aadọjọ ọdun bẹẹ si ni eyi ti eeyan ti ri ri to ju bẹẹ lọ ṣaaju ti Alagba ni o lo Igba ọdun laye.
Ẹwẹ, Alagba ṣe o lo odidi ọdun mejilelọọdunrun loke eepẹ ko to faye silẹ.
Lara ohun ti ẹ ko mọ nipa oloogbe ijapa to wa lafin Ṣọun Ogbomoso ree.
- Alagba ni orukọ rẹ, o ni awọn òṣìṣẹ́ lati aafin Kabiyesi to n tọju oun nikan. Oṣiṣẹ meji tabi ju bẹẹ́ lọ lo n tọju oun nikan. Lati kekere ni awn kan ti n tọju rẹ ti wọn si dagba sẹ́nu ẹ.
- Baba Kabiyesi oni to jẹ Jagunjagun lo pade rẹ leti igbo to si mu u bọ wale latoju ogun.
- Gbogbo ounjẹ ti eniyan n jẹ loun naa n jẹ to fi mọ eso bii Ọpọ Oyinbo, Ibẹpẹ,Ọgẹdẹ. bakan naa, o n jẹ Amala, Irẹsi, Dodo ati Ẹwa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Àìṣàn ráńpẹ́ ṣekú pa ijàpà ẹni ọdún 344 ní Ààfin!
- MC Oluọmọ ti di Alága àwọn awakọ̀ ní ìpínlè Èko. MC Oluọmọ ti di Alága àwọn awakọ̀ ní ìpínlè Èko.
Agba Inaki n ṣe'daro Alagba
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
- Ijapa Ogbomoso dagba ju gbedeke iye ọjọ ori tawọn onimọ ni o yẹ ki Ijapa kan lo laye lọ.
- Wọn ko gun un ni abẹ́rẹ́ ri tabi ki awọn onimọ iṣegun oyinbo ṣe ayẹwo fun un ri.
- Ẹẹmeji pere ni Alagba maa n jẹun laarin oṣu kan kii sii sunmọ ẹnu ibode ọgba rẹ ayafi bo ba fẹ mu omi. Eyi ni wọn fi n mọ pe omi lo fẹ.
- Awọn eeyan a ma lọ sọdọ ogbologbo Ijapa yii lati tọrọ ẹbẹ adura to si n wa si imuṣẹ
Àwọn àrídájú 'ọ̀rọ̀ yìí wá látẹ́nu akọ̀wé àgbà Toyin Ajamu ní ààfin Kábíyèsí Ṣọun ti ilu Ogbomosho fún BBC Yorùbá.










