MC Oluomo: Ẹgbé Awakọ lpińlẹ Èko yan Musiliu Ayìndé Akínsànyà bíi Adarí.

MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, MC Oluomo/Facebook

Musiliu Ayinde Akinsanya ti gbogbo eniyan mọ si MC Oluomo ni wọn ti fi jẹ oye ọga awọn awakọ NURTW ni Ipinlẹ Eko.

MC Oluọmọ ni o ti kọkọ fi igba kan jẹ ọmọ egbe awakọ ni agbegbe Oshodi ni Ilu Eko to si jẹ mọlumọọka.

Won fi si ori oye yii gẹgẹ bi adari fun igba diẹ latari lile ti awọn olori agba egbe naa le awọn ti o wa nibẹ tẹlẹ kuro.

Ṣe saaju ni awọn kan ti kora jọ ni bii Ọsẹ diẹ sẹyin lati fi ẹhonu han lori fifi MC Oluọmọ jẹ alaga fidihẹ ẹgbe naa.

Awọn ti o fi ehonu han yii lọ si iwaju lle lgbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lati fariga lori iyansipo rẹ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.

Ẹni ti o jẹ alaga agba fun ẹgbẹ NURTW, Alhaji Tajudeen Ibikunle Baruwa ni o yan an ti o si fa a kalẹ.

Alaga tuntun fun awọn awakọ ni Ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, facebook

Àkọlé àwòrán, Musiliu Ayinde Akinsanya MC Oluọmọ

Tajudeen Agbede ni o jẹ adari ẹgbẹ naa tẹlẹ ṣugbọn ti o ti wa di Igbakeji Aarẹ ẹgbẹ ni Orilẹ ede Naijiria.

Musiliu Ayorinde Akinsanya ti gbogbo eniyan mọ si MC Oluọmọ jẹ alaga fun ẹka ẹgbẹ naa tẹlẹ ni agbegbe Oshodi ki o to di Alaga fidihẹ bayii.

Ni bayii, ọmọ ẹgbẹ mẹtadinlogun ni yoo maa ba a ṣiṣẹ titi di igba ti wọn yoo fi ṣe eto ifinisipo to peye.

Àkọlé fídíò, Imam tó ṣí Mọ́ṣálásì fáwọn Krístẹ́nì sọ ìdí tí kò fi lè ta wọ́n nù