Ẹ̀dà ìwé ìdájọ́ tó rán Ọba Ipetumodu lẹ́wọ̀n l'Amerika tẹ àwọn ìdílé ọba lọ́wọ́.

Oríṣun àwòrán, @BritoCurrency
Idile ọba meji to n jẹ oye ọba niluu Ipetumodu nipinlẹ Osun, ti tẹwọgba ẹda iwe idajọ lati orilẹede Amẹrika, eyi to sọ Ọba ilu naa, Apetu ti ilu Ipetumodu, Ọba Joseph Oloyede si ọgba ẹwọn fun ọdun marun un lori ẹsun iwa ibajẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ori ade yii, ẹni ọdun mejilelọgọta ni wọn gbe idajọ rẹ kalẹ ni ọjọ kẹrindinlọgbọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025, pe o jẹbi ẹsun iwa ibajẹ, ti adajọ Christopher A. Boyko si ju si ẹwọn ọdun marun un.
Bakan naa ni wọn ni ki ori ade naa tun lọ lo ọdun mẹta miran sii, ko tun san apapọ owo to jẹ $4,404,543.38.
Gẹgẹ bii agbẹjọro ijọba amẹrika to jẹ olupẹjọ ṣe ṣalaye, ori ade yii ni wọn gba ile rẹ ni Medina, Ohio, ati awọn ile to ra pẹlu owo yii, pẹlu owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla owo ilẹ Amẹrika, $96,006,89.
Lẹyin idajọ yii, ijọba ipinlẹ Osun ni awọn ko ni gbe igbesẹ kankan lori yiyọọ loye gẹgẹbi awọn kan ni ilu naa ṣe n pe fun nitori nnkan ti awọn eeyan n sọ lori ayelujara.
Lẹyin to ku diẹ ko pe oṣu mẹfa, awọn idile yii jẹ ko di mimọ pe awọn ti tẹwọgba ẹda iwe idajọ lẹyin ti wọn kọ lẹta pe awọn nilo rẹ.
Olaboye Ayoola, aṣoju awọn mọlẹbii ọba sọ pe idile mejeeji yoo yan awọn aṣoju ti yoo lọ ba Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ṣe ipade lati mọ igbesẹ to kan.
"A beere ẹda iwe idajọ yi ninu lẹta kan ti Ọmọọba Taiwo Ayoola buwọlu lọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 si akọwe ile ẹjọ ni Amẹrika.
"Pẹlu bii kọmiṣọna ileeṣẹ ọlọpaa, Ibrahim Gotan ṣe da si ọrọ yii, a fopin si erongba wa lati ṣe ifẹhonuhan lori bi a ko ṣe ni ọba."
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ọba to lu jibiti naa ree
Oba Joseph Olugbenga Oloyede ni Apetumodu kẹtadinlọgbọn ilu Ipetumodu nipinlẹ Osun.
Ọdun 2019 lo gori aleefa lẹyin ti Ọba James Adedokun Adegoke waja ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2017.
O kẹkọọ alakọbẹrẹ nile ẹkọ Christ Church II ati C & S Modern Commercial Secondary School niluu Ipetumodu.
Itan sọ pe o kẹkọgboye ninu imọ iṣiro nile ẹkọ gbogboniṣe ilu Ibadan ko to lọ si fasiti ijọba ipinlẹ Enugu lati kẹkọọ siwaju si.
Lẹyin naa lo lọ silẹ Amẹrika lati kẹkọọ ni fasiti Sarasota, ni Florida nibi to ti gba oye MBA.
O tun gba oye ọmọwe, Doctor of Business Administration (DBA) ni Argosy University, Sarasota.
Lara awọn ibi to ti ṣiṣẹ ni ile ifowopamọ First Bank of Nigeria ati John Holt Financial Merchant Bank ko to pada silẹ Amẹrika.
Ọmọ oye Aribile ni lati idile Latimogun ko to gori itẹ ilu Ipetumodu.

























