Ìjọba fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ alákatakítí ẹ̀sin Islam pé wọ́n ṣekúpa èèyàn 34 ní àwọn abúlé káàkiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Mansur Abubakar
- Reporting from, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
O le ni eeyan mẹrinlelọgbọn ti ikọlu awọn adijagbara awọn ẹgbẹ alakakiti ẹsin Islam ti ṣekupa ni awọn abule kaakiri apa ariwa orilẹede Naijiria, awọn alaṣẹ sọ fun BBC.
Awọn agbebọn ya wọ awọn abule ni ọna ibode ipinlẹ Kebbi lọjọ Iṣẹgun, ti wọn si kapa awọn ẹsọ alabo awọn abule naa, ti awọn araalu si ni lati ṣe kuro ni ile wọn.
Awọn ti ori koyọ ṣapejuwe to ṣe ikọlu gẹgẹ bii ti awọn akọsẹmọsẹ, ti wọn si n yin ibọn kaakiri gbogbo ile.
Awọn alaṣẹ ti na ika abuku si ẹgbẹ alakakiti ẹsin Islam tuntun, Lakurawa, ti wọn ṣe n ṣiṣẹ ni awọn agbegbe naa.
O wa lara ikọ agbebọn ti ado oloro Amẹrika gbero lati kọlu nipinlẹ Sokoto ninu oṣu kejila ọdun to kọja.
Awọn ẹlẹsọ alabo ti gbera lọ si awọn agbegbe naa lati pe aabo fun awọn araalu ati ran wọn lọwọ pẹlu.
Awọn alaṣẹ ko ti sọrọ nipa awọn ikọlu yii, bo ti lẹ jẹ pe awọn aworan oku awọn eeyan ti wọn gbe wọ kalẹ ti pọ lori ayelujara.
Ikọlu yii ti fa ọpọ ariyanjiyan lori ayelujara, ti ọpọ ọmọ Naijiria si n kesi ijọba lati fopin iwa iṣekupani yii, eyi to wọpọ ni awọn agbegbe kan ni orilẹede Naijiria.
Ọdun to kọja ni ijọba Naijiria kede Lakurawa gẹgẹ bii ikọ agbesunami, ti wọn si fofin de wọn kaakiri lẹyin ti iroyin jade pe ikọ n lu awọn eeyan nitori wọn n gbọ orin.
Ikọ Lakurawa jẹ ẹgbẹ alakatakiti ẹsin tuntun to n fẹmi awọn eeyan ṣofo lapa iwọ-oorun ariwa Naijiria papaa julọ lẹkun ibode Naijiria ati orililẹede Niger.
Ijọba Naijria gbagbọ pe ẹgbẹ Lakurawa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin kan lorilẹede Mali.



























