Ìjọba àpapọ̀ kéde ikọ̀ agbébọn Lakurawa tó ń ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ ti kede ikọ Lakurawa to n ṣọṣẹ lapa ariwa orilẹede Naijiria gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi.
Ikọ Lakurawa jẹ ẹgbẹ alakatakiti ẹsin tuntun to n fẹmi awọn eeyan ṣofo lapa iwọ-oorun ariwa Naijiria papaa julọ lẹkun ibode Naijiria ati orililẹede Niger.
Ijọba Naijria gbagbọ pe ẹgbẹ Lakurawa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin kan lorilẹede Mali.
Ẹgbẹ Lakurawa yii ni igbagbọ wa pe wọn ti wọ Naijiria tipẹ ti wọn si ti n fẹ awọn ọmọbinrin Naijiria ni iyawo.
Awọn ẹgbẹ Lakurawa yii ni igbagbọ tun wa pe wọn ti n ko awọn ọdọkunrin ọmọ Naijiria ti wọn n lo jọ tipẹ.
Iwe akọsilẹ kan to ṣalaye bawọn ẹgbẹ Lakurawa sẹ n ṣọṣẹ ni ijọba sẹ afihan rẹ nile ẹjọ giga niluu Abuja lanaa Ọjọbọ.
Gẹgẹ bi ohun to wa ninu akọsilẹ ọhun, ẹgbẹ Lakurawa ti n ji eeyan gbe pawo, bẹẹ ni wọn tun n ji maalu gbe.
Bakan naa ni akọsilẹ iwe ti ijọba fi han nile ẹjọ tun sọ pe ẹgbẹ Lakurawa n ṣe ikólu sawọn ẹṣọ ọmogun atawọn oṣiṣẹ ijọba.
Ẹgbẹ Lakurawa yii ni ijọba tun fẹsun kan wi pe wọn kọ araalu lodi ẹkọ nipa ẹsin musulumi ti wọn si n sọ fun wọn lati tako ijọba orilẹede Naijiria.
Igbesẹ yii ni a gbọ pe o jẹ ki ọpọ eeyan padanu ẹmi wọn ati dukia.
Minisita eto idajọ to tun jẹ agbẹjọro agba ni Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN), sọ pe awọn nnkan ti ẹgbẹ Lakurawa n ṣe le ṣakoba nla fun eto aabo Naijiria, bakan naa ni ohun ti wọn n ṣe le da omi alaafia orilẹede ru.
Lẹyin gbogbo atotonu agbọjọro ijọba ni adajọ James Omotosho kede Lakurawa gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesumọmi ni Najiria ti o si fofin de wọn papaa julo lẹkun iwọ oorun ariwa ati aarin gbungbun ariwa orilẹede Naijiria.
Igbesẹ yii jẹ nnkan ti ijọba Naijiria le lo lati fi gbogbo agbara to ba ni kọju ija si ẹgbẹ Lakurawa.
Ni bayii, awọn ẹṣọ eleto aabo le fọwọ ofin mu awọn ikọ Lakurawa ati gbe wọn lọ ile ẹjọ.
Awọn wo lo wa nidii ikọ agbebọn Lakurawa?
Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Sokoto n kọminu nipa ẹgbẹ agbesunmọmi kan to n ṣọṣẹ ni ijọba ibilẹ marun un nipinlẹ naa.
Igbakeji gomina ipinlẹ Sokoto, Alhaji Idris Muhammad, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ọrọ rẹ lasiko abẹwo awọn akẹkọọ ileeṣẹ ọmogun si ipinlẹ naa laipẹ yii.
Alhaji Muhammad sọ fun BBC pe awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa ti wọn ni ohun ija oloro lọwọ n waasu fawọn olugbe ilu bii Tangaza, Gudu, IIIela, Binji atawọn abule kan ni Silame.
Nibo lẹgbẹ Lakurawa ti wa?
Ẹnikan ti ko fẹ ki BBC darukọ oun sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa wọ Sokoto lati ẹkun Sahel to de awọn orilẹede bii Mali ati Niger.
Ẹgbẹ alakatakiti ẹsin yii n sọ fawọn eeyan kaakiri ni ipinlẹ Sokoto wi pe ki wọn ma gba awọn ọlọpaa ati ologun laaye, ki wọn si tun tako lilọ ile ẹkọ.
Awọn ẹgbẹ yii ni a gbọ pe oniruuru ede ni wọn fi n ba awọn eeyan sọrọ.
Akọsilẹ fihan pe awọn eeyan yii n waasu, wọn si n kilọ nigba tawọn kan si n ṣe ogbufọ fun wọn lede Hausa, Fulani, Abzinanci, Tubanci, Barbari, ati lede oyinbo gan an.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa yii ni wọn sọ pe wọn pọ gan an, ẹnikan sọ fun BBC pe o maa n to bii ọkọ mẹwaa si mẹẹdogun ti wọn maa n di mọra ti wọn ba n wọ inu ilu lọ.
Akọsilẹ fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ṣe agbekalẹ ofin tawọn eeyan n tẹle fun araalu, bakan naa ni wọn tun n ṣe eto irolagbara pẹlu iranwọ owo Sefa fawọn ọdọ.
Ko tan sibẹ o, awọn eeyan yii tun n gba owo ori ati saka.
Wọn maa n gbe ẹran ọsin ẹnikẹni to ba kọ lati san owo ori ati saka lọ ni titi ẹni naa yoo san an.
Olugbe agbegbe tawọn alakatakiti ẹsin yii ti n ṣọṣẹ kan sọ fun BBC wi pe ijọba ibilẹ meji ni wọn ti n ṣọṣẹ julọ nipinlẹ Sokoto.
O ṣalaye pe ko si ibi tawọn alakatakiti ẹsin yii kii de yatọ si olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ Gudu.
Laipẹ yii ni a gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa yii ṣe ikọlu sawọn ọmogun Naijiria nibi ti eeyan mẹrin ti ku.
Kí ni ìtumọ igbesẹ ijọba apapọ lori ẹgbẹ Lakurawa?
Agbẹjọro Bulama Bukarti, onimọ nipa eto abo ni agbegbe Sahel kan sara si ijọba apapọ fun igbesẹ to fofin de ẹgbẹ Lakurawa, to si kede wọn gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunami.
"Gbogbo ohun ti awọn ẹgbẹ agbesunami n se ni ẹgbẹ Lakurawa n se.
O wa se akọsilẹ ohun mẹfa ti yoo sẹlẹ si ẹgbẹ naa bi ijọba se fofin de wọn.
Ẹnikẹni ko gbọdọ darapọ ẹgbẹ naa
Agbẹjọro Bukarti ni fifofin de ẹgbẹ Lakurawa tumọ si pe ẹnikẹni to ba ni ajọsepọ pẹlu ẹgbẹ ti di ọdaran, to si ti tapa si ofin Naijiria.
"Orilẹede Naijiria faya gba araalu lati da ẹgbẹ tabi darapọ mọ ẹgbẹ ṣugbọn ti ijọba ba ti kede pe ẹgbẹ naa ti ẹgbẹ agbesunami, didarapọ mọ ẹgbẹ naa lo ti di eewọ.
"Ẹwẹ sise atilẹyin fun wọn naa jẹ sisẹ si ofin Naijiria."
Saaju ki ijọba to fofin de wọn, ọpọ ohun ti ẹgbẹ naa n se ni ijọba ko sọrọ ayafi ti wọn ba sẹ si ofin
Kiko gbogbo ohun to jẹ ti ẹgbẹ naa
Pẹlu bi wọn se kede ẹgbẹ Lakurawa gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunami bayii, gbogbo ti o jẹ ti wọn ni ijọba yoo gbe ẹsẹ le.
"Ti wọn ba ni ile ifowopamọ, yoo di titi pa. Wọn lw gba ilẹ lọwọ, pẹlu awọn ọkọ. Koda wọn le ma ni anfani lati rin irinajo.
Ki koju awọn ọmọ ologun
Ki wọn to kede ẹgbẹ Lakurawa gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunami, awọn ọmọ ologun ko ni anfani pupọ lati gbe oogun ti wọn.
"Ni bayii ti ijọba ti fun ileeṣẹ ologun ni aṣẹ tuntun lati gbe ogun ti awọn ẹgbẹ agbesunami, ija yoo bẹ silẹ ti wọn yoo si nilo awọn ohun ija nla.
Didena de iranlọwọ fun ẹgbẹ naa
Ni bayii gbogbo iranlọwọ to ba ti ọwọ ẹgbẹ Lakurawa ni ijọba yoo de na de, ti wọn yoo si ri gẹgẹ bii ija.
Awọn ileeṣẹ to n ran ni lọwọ ni anfani lati ran awọn ẹgbẹ naa lọwọ sugbọn pẹlu ofin, ko ni si anfani naa.
Pipadanu ajọsepọ agbaye
Pẹlu bi wọn se kede ẹgbẹ naa bayii, awọn orilẹede agbaye yoo ma bẹrẹ si ni sa fun wọn tabi ba wọn ni ohunkohun papọ.
"Fun apẹẹrẹ, ajọ isọkan bi ECOWAS, AU ati awọn yooku le gbe ẹsẹ le dukia ẹgbẹ naa, ki wọn si ma ni anfani lati wọ orilẹede kankan. Gbogbo ohun ti ẹgbẹ Lakurawa ba se bayii lo ti di ohun to tapa si ofin.
Ikikọ fun awọn araalu lati yago fun ẹgbẹ naa
Ọpọ awọn araalu yoo bẹrẹ si ni ma sa fun awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa bayii nitori o ṣeeṣe ki wọn gbe ogun ti wọn.
"Ikede yii ti da epo si asọ ala ẹgbẹ Lakurawa ni awujọ bayii, ti ọpọ ko si ni fẹ darapọ mọ wọn. Bẹrẹ lati ori awọn ọdọ to ba bifẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ naa



























