Ǹjẹ́ Alaafin Oyo tuntun lè rìnrìn àjò lọ sókè òkun láì tíì wọ Ìpẹ̀bí? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Akin Abubakri/X
Ọpọ eeyan lo ti n kọminu lori iroyin kan to sọ pe Alaafin oyo tuntun, Ọba Akeem Owoade, ti pada si orilẹede Canada to fi ṣe ibugbe lẹyin ti Gomina Seyi Makinde gbe ọpa aṣẹ fun un tan.
Lọjọ kẹtala oṣu Kinni ọdun yii ni Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Alaafin Owoade ni ọfiisi gomina niluu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo.
Tilu tifọn lawọn eeyan fi ki kabiyesi kaabọ nigba to wọ ilu Oyo lẹyin to gba ọpọ aṣẹ tan.
Titi pa ni gbogbo ọja wa lati fi ṣe ayẹsi Alaafin Oyo tuntun, Ọba Owoade.
Amọ, ni nnkan bi ọjọ meji bayii ni iroyin kan sọ pe Ọba Owoade ti pada si orilẹede Canada nibi to ti wa jọba.
''Alaafin Oyo tuntun ko tapa si aṣa to ba lọ irin ajo''
Agbaọjẹ babalawo to tun jẹ adari tẹlẹ fun ile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo, Ọjọgbọn Wande Abimbola, sọ fun iwe iroyin Tribune pe Alaafin Oyo ko tapa si ofin ati aṣa Yoruba nipa irinajo rẹ lọ si Canada lẹyin to gba ọpa aṣẹ tan.
Ọjọgbọn Abimbola ṣalaye ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Tribune pe ''ipebi atawọn eto mii ti wọn maa n ṣe fun ọba ko tii bẹrẹ, tori naa Alaafin Owoade ko tasẹ agẹrẹ si aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.
Awọn afọbajẹ atawọn babalawo lo maa sọ asiko ti ipebi ati awọn eto mii yoo bẹrẹ.''
Ọjọgbọn Abimbola to difa to mu Ọba Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun ṣalaye pe Ifa lo maa n sọ ọjọ ti Ipebi yoo bẹrẹ laye atijọ.
Amọ, o sọ pe awọn Oyemesi atawọn babalawo lo maa n sọ igba ti Alaafin tuntun yo wọ Ipebi laye ode oni.
Ninu ọrọ tiẹ, adari awọn ijoye, Oloye Mukaila Atanda ti ọpọ mọ si Baba Iyaji, naa fidi rẹ mulẹ fun iwe iroyin Tribune pe Alaafin Oyo tuntun ko tii bẹrẹ Ipebi atawọn eto mii ti yoo ṣe.
O ni kabiyesi ti pada si Canada, ti o ba pada de lo maa wọ Ipebi.
Nàíjíríà ló yẹ kí wọ́n ti dá ifá tí yóò yan Ọba ilẹ̀ Yoruba, kìí ṣe ìlú èèbó - Oba Ogboni

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Ero awọn ọmọ Yoruba ti se ọtọọtọ lori iyansipo Alaafin tuntun, Ọba Abimbola Akeem Owoade, paapaa lori ilana ti ijọba ipinlẹ Oyo gba lati yan ọmọọba naa sori oye.
Awuyewuye yii ko si sẹyin fidio kan to lu sori ayelujara nibi ti adari tẹlẹ fun ile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo, Ọjọgbọn Wande Abimbola to jẹ ọmọ bibi ilu Oyo ati babalawo to fi ilẹ Amẹrika se ibujoko bayii, ti da Ifa lati mọ ẹni ti yoo jẹ Alaafin.
Gẹgẹ bi Abimbola ti wi, Ọmọọba Abimbola Akeem Owoade ni odu rẹ kun julọ laarin awọn ọmọ oye, ti Ifa si mu gẹgẹ bii Alaafin Kẹrinlaadọta.
Gẹgẹ bi Fidio naa se wi, ijọba ipinlẹ Oyo lo ni o gbe isẹ dida Ifa lati yan Alaafin tuntun fun Wande Abimbola.
Ọrọ yi ni ko dun mọ awọn eeyan kan ninu, ti wọn si n beere pe se o tọna lati da Ifa fun yiyan Ọba ilẹ Yoruba lati ilẹ okeere?
Bakan naa, ni wọn koro oju si sise ayẹyẹ igbọpa asẹ ati iwe ẹri ni bonkẹlẹ ni ọọfisi gomina, tawọn igbesẹ iyansipo Alaafin tuntun naa ko si lọwọ awọn afọbajẹ nilu Oyo ninu.
Yatọ si eyii, awuyewuye mii to tun n jẹyọ ni ti awọn Oyomesi marun ti ajọ EFCC fi ẹsun gbigba riba kan lọna ati yan ọmọ oye ti wọn n fẹ.
Eredi ree ti BBC Yoruba fi kan si ẹni to mọ kulẹkulẹ aṣa ilẹ Yoruba lati sọrọ lori bi wọn ṣe n difa yan ọmọ oye fun ipo ọba, se wọn le e difa loke okun lati yan mọ oye?
Bakan naa, a fẹ mọ boya o ba asa mu lati lọ mu ọmọ oye to n gbe loke okun pe ko wa jba nile, atawọn nnkan mii to ti jẹyọ lẹyin ti wọn yan Alaafin Owoade.















