Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìdájọ́ ikú fún Ramon Adedoyin fún ipa tó kó nínú ikú Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Ramon Adedoyin/Facebook
Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja ti fontọ lu idajọ iku fun adari ileeṣẹ ile itura Hilton Hotels ni Ile Ife nipinlẹ Osun, Dokita Ramọn Adedoyin, lori ọrọ iṣekupani akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke to ku si ile itura rẹ.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to jokoo l'Ọjọbọ niluu Akure fi ontẹ lu idajọ iku eyi ti ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Osun ti da tẹlẹ fun Adedoyin.
Lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe agbekalẹ idajọ naa ki o to ka a lonii Ọjọbọ ọjọ kẹtalelogun oṣu Kinni ọdun yii.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Akure sọ pe ''a duro lori idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun lori ọrọ yii.
Fun idi eyi, ile ẹjọ kotẹmilọrun yii ti yi ẹjọ Adedoyin danu.''
Ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe ko si aṣiṣẹ ninu idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to dajọ iku fun gbajugbaja oniṣowo Adedoyin.
Ile ẹjọ ni idajọ iku ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun da tẹlẹ fun Adedoyin tọna labẹ ofin pẹlu nnkan to ṣẹlẹ.
Amọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun fagile idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to gbẹsẹ le ile itura Hilton Hotel to jẹ ti Adedoyin.
Bakan naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tun fagile idajọ ile ẹjọ giga to paṣẹ pe ki Ọgbẹni Adedoyin maa sanwo ile ẹkọ awọn ọmọ oloogbe Timothy Adegoke.
Ninu oṣu Kọkanla ọdun 2021 ni iroyin iku Timothy jade lẹyin ti wọn ri oku rẹ nile itura Hilton hotel niluu Ile Ife to wa.
Ramon Adedoyin mori le ile ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin ti ile ẹjọ giga dajọ iku fun un
Adari ileeṣẹ ile itura Hilton Hotels ni Ile Ife nipinlẹ Osun, Dokita Ramọn Adedoyin gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ lẹyin ti adajọ da ẹjọ iku fun lori iṣekupani akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke.
Ileẹjọ giga nipinlẹ Osun lo da ẹjọ pe ki wọn yegi fun nitori o lọwọ ninu iku arakunrin naa to sun si ile itura rẹ.
Ti a ko ba gbagbe, adajọ Adepele Ojo lo ran Adedoyin ati oṣiṣẹ rẹ meji ti wọn gbe oku naa kuro ni ile itura naa, Adeniyi Aderogba ati Oyetunde Kazeem pe ki wọn yẹ igi fun.
Bakan naa ni adajọ ni ijọba ti gbegile ile itura naa, ti o si ti da ti ijọba.
Adajọ tun ni ohun ini Adedoyin ni wọn yoo fi ran awọn ọmọ Adegoke lọ si ileẹkọ titi wọn yoo fi jade fasiti.
Amọ adajọ naa fi awọn oṣiṣẹ mẹta silẹ, Magdalene Chiefuna, Oluwole Lawrence ati Adebayo Kunle ki wọn maa lọ ni alaafia, ti akọwe to wa ni ibi isẹ naa si gba idajọ ẹwọn ọdun meji fi jura.
Nibayii ni Ramon Adedoyin ti ni oun ko faramọ idajọ iku naa, to si ti gba ileẹjọ naa.
Ọkan ninu awọn adajọ Adedoyin, Adajọ agba Kunle Adegoke lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Bakan naa lo ni ileẹjọ kotẹmilọrun ni ilu Akure, nipinlẹ Ondo ni wọn gbe ẹjọ naa lọ.















