Àwọn èèyàn máa ń fi mí wé Yinka Ayefele, kódà a jọ ń lo kẹ̀kẹ́ ni ṣùgbọ́n ìyàtọ́ wà níbẹ̀ – Akin Omo Akin, gbajúmọ̀ olórin

Àkọlé fídíò, Àwọn èèyàn máa ń fi mí wé Yinka Ayefele, kódà a jọ ń lo kẹ̀kẹ́ ni ṣùgbọ́n ìyàtọ́ wà níbẹ̀ – Akin Omo Akin
Àwọn èèyàn máa ń fi mí wé Yinka Ayefele, kódà a jọ ń lo kẹ̀kẹ́ ni ṣùgbọ́n ìyàtọ́ wà níbẹ̀ – Akin Omo Akin, gbajúmọ̀ olórin

Bi eeyan ba ri gbajumọ akọrin Akin ọmọ Akin ati eekan akọrin oun agbohunsafẹfẹ, Yinka Ayefẹlẹ, awọn afijọ kan wa nibẹ ti awọn ololufẹ wọn pẹlu ti n ṣe akiyesi.

Koda ninu orin wọn, awn eeyan ti n tọka si afijọ to wa nibẹ.

Eekan akọrin ni Akinbọtẹ Akinyẹmi ti ọpọ eeyan mọ si Akin Ọmọ Akin.

Amọṣa Akin Ọmọ Akin ṣalaye pe ti awọn eeyan ba fi arabalẹ daadaa si orin ti oun nkọ wọn a rii pe iyatọ wa laarin iṣọwọ kọrin wọn.

'Aarun rọparọsẹ 'polio' lo sọ mi di ero ori kẹkẹ'

Ninu ifọrọwerọ rẹ, o ni kii ṣe bẹẹ ni wọn ṣe bi oun. O ni aarun rọparọsẹ lo mu oun nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun marun un to fi di rọparọsẹ.

"Ni ọdun yẹn, mo ri pe ara mi n gbona, awọn baba mi ati iya mi si gbe lọ si ileewosan, nigba ti a dẹ maa de, nnkan ti emi mọ mọs ni pe mo ba ara mi ni ipo yii mi o le rin mọ"

Afiwe Akin ọmọ Akin ati Ayefẹlẹ

Akin ọmọ Akin sọ pe ọpọ igba lawọn eeyan ti maa n fi oun we Yinka Ayefẹlẹ ti oun pẹlu jẹ akọrin to si tun ni ipenija ẹsẹ pẹlu.

O ni lootọ lawọn eeyan rii pe afijọ wa lara orin oun ati orin Ayefẹlẹ, sibẹ bi wọn ba wo o daadaa, wọn a rii pe iyatọ to pọ wa nibẹ.

Bakan naa lo fi kun un pe lọpọ igba lawọn kan ti wọn fẹ gbe oun lọ si oke okun fun ere nigba kan yọwọ nigba ti wọn si maa ṣalaye, wọn ni awọn ko fẹ ṣẹ eeyan kan lsn fi jawọ ninu igbesẹ naa.