Ìdí tí mo fi pín ewúrẹ́ 7,158 fún obìnrin 2,386 ní Kano - Gómìnà Yusuf

Aworan gomina Kano atawọn obinrin

Oríṣun àwòrán, Abba Kabir Yusuf/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Abba Yusuf ipinlẹ Kano ti ṣalaye idi to fi fawọn obinrin 2,386 nipinlẹ naa ni ẹran ọsin ewurẹ 7,158 lọsẹ yii.

Gomina Yusuf ṣalaye loju opo X rẹ pe oun ṣe eleyii lati ro awọn obinrin ipinlẹ naa lagbara.

Gomina ni abala keji eto ironilagbara ijọba oun nipa ẹran ọsin ni eto yii jẹ.

Gomina Yusuf ṣalaye wi pe gbogbo ijọba ipinlẹ mẹrinlelogoji to wa ni ipinlẹ Kano lawọn obinrin to jẹ anfaani gbigba ẹran ọsin yii ti wa.

O ni ijọba oun ṣe eleyii lati ṣe iranwọ fawọn obinrin to n da ṣe iṣẹ ara wọn ṣe nipinlẹ Kano.

Gomina Kano ni eto yii tun jẹ ọkan lara ọna ti ijọba oun n lo lati mu adinku ba iṣẹ ati oṣi to n ba ọpọ eeyan finra nipinlẹ Kano.

O ni lẹyin ti ijọba oun ti pin ewurẹ to le lẹgbẹrun meje fawọn obinrin tan, gomina ni ijọba oun yoo tun pin maalu 1,342 ati ẹran agbo 1,822 fawọn obinrin ati ọdọkunrin to ba ya.

''Ohun ti a fẹ ṣe pẹlu eto yii ni pe a fẹ ki idile kọọkan maa ṣiṣẹ rowo funra wọn, ko ma jẹ wi pe lọwọ ijọba nikan ni wọn ti maa beere iranwọ ni gbogbo igba,'' Gomina Kano lo sọ bẹẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bakan naa ni ijọba Kano tun ro awọn to ṣẹṣẹ kẹkọọ gboye jade nile ẹkọ ti wọn ti m kọni nipa nnkan ọsin ati gbigbin ododo ni Bagauda.

Gomina Yusuf fun ojilenirinwo akẹkọọgboye ile ẹkọ naa ni awọn irinṣẹ ti wọn nilo, ẹrọ to n gbomi wa soke lati inu ilẹ, aye ti wọn ti le maa ṣiṣẹ wọn pẹlu N100,000 lati ra nnkan ọgbin.

Gomina tun tun ro awọn akẹkọọgboye 140 lati ile ẹkọ nnkan ọsin lagbara, aadọta ninu wọn gba maalu meji meji, nigba ti aadọrun gba agbo meji meji.

Ijọba tun fun awọn akẹkọọgboye naa ni ounjẹ nnkan ọsin ti wọn le lo fun oṣu mẹta ati N100,000 lati ra nnkan ọgbin.