Àwọn nǹkan tó lè mú kí ẹlẹ́wọ̀n tó ti gbòmìnira dèrò ẹ̀wọ̀n padà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onimọ nipa ihuwasi ẹda ati afi iṣe mọ iwa ẹda, Dare Omowunmi, ti ṣalaye ohu n ti le fa a ki ẹlẹwọn to ti gbominira tun pada dero ẹwọn.
Ọrọ naa nii ṣe pẹlu Sunday Omisakin to wa lara awọn ẹlẹwọn ti Gomina Ademola Adeleke da silẹ loṣu Kejila ọdun 2024, eyi to tun dero ẹwọn pada lẹyin ọjọ diẹ to gba ominira.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Arabinrin Omowunmi sọ pe awọn ilana ati igbesẹ kan wa to yẹ ki ijọba gbe lori awọn to wa lẹwọn lasiko ti wọn ba wa nibẹ.
''Kii ṣe wi pe ki wọn kan ju wọn sẹwọn ki wọn kan wa nibẹ lai ṣe eto kankan fun wọn.
O yẹ ki ijọba gba awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn mọ bi wọn ṣe maa tọju wọn, nitori pe nnkan kan lo ṣokunfa bi awọn eeyan ṣe dero ẹwọn tẹlẹ.
Bo ya ebi lo n pa a nigba naa to fi lọ jale to si dero ẹwọn lati ibẹ, tabi bo ya nnkan mii lo sun un de ibẹ,'' Omowunmi ṣalaye.
O fikun ọrọ pe o yẹ ki ijọba maa lo awọn akọṣẹmọṣẹ afiṣe mọ iwa ẹda lati ba awọn ẹlẹwọn sọrọ lasiko ti wọn ba wa lẹwọn.
''Akọṣẹmọṣẹ ihuwasi ẹda gbọdọ maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹlẹwọn lọgba ẹwọn''
Afiṣe mọ iwa ẹda Omowunmi ni ọrọ Omisakin to tun dero ẹwọn lẹyin to gbominira tumọ si pe ihuwasi ati oye rẹ ko yi pada.
Omowunmi sọ pe ọpọ ẹlẹwọn to gba ominira kan pada si igboro ni lai si eto kankan fun wọn.
"Ka ni pe oye rẹ ati bi o ti n ronu ti yi pada lasiko to wa ninu ọgba ẹwọn ni, iṣẹ to ba ti kọ lati ọgba ẹwọn ni ijọba ko ba ran an lọwọ lati maa ṣe lẹyin to gbominira tan.
Ti akọṣẹmọṣẹ afi iṣe mọ iwa ẹda ba ti ṣiṣẹ pọ pẹlu iru eeyan bẹẹ lọgba ẹwọn ni, ero ọkan rẹ nipa igbesi aye ko ba ti yatọ.
O ti maa ni iriri nipa bi yoo ti gbe ile rẹ to ba jade lọgba ẹwọn, kii ṣe wi pe o kan maa wa lọgba ẹwọn nikan,'' Omowunmi lo sọ bẹẹ.
Onimọ nipa ihuwasi ẹda naa wa rọ ijọba lati maa ri pe oriṣiiriṣii awọn akọṣẹmọṣẹ nipa iwa ẹda n bawọn sọrọ lasiko ti wọn wa lọgba ẹwọn.















