Wo iye tí yóò gun orí owó ìpè àti dátà rẹ lẹ́yìn tí ìjọba Nàìjíríà buwọ́lu àfikún tàríìfù tuntun

Aworan ọkunrin to gbe foonu seti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Owo ipe lori foonu ati data yoo lọ soke ni Naijiria lẹyin ti ajọ NCC to n ri si eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria ti buwọlu aba awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ lati ṣe afikun owo tariifu tawọn onibaara wọn n san.

Ida 50% ni awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ yoo fi ṣe afikun owo ipe ati data naa.

Ajọ NCC ṣalaye pe afikun ida 50% yoo waye nitori bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori lẹkun ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ajọ NCC, Reuben Muoka, ni o ti ṣalaye pe afikun tariifu yii wa ni ibamu pẹlu apa 108 to sọ nipa ẹrọ ibaraẹnisọrọ ninu iwe ofin orilẹede Naijiria.

Ọgbẹni Muoka sọ pe awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ lo pe fun afikun owo tariifu eyi ti ajọ NCC si ti buwọlu.

Eleyi tumọ si afikun yoo ba iye tawọn araalu n ra data tabi kaadi ipe.

Agbẹnusọ ajọ NCC sọ pe ida 100% lawọn ileesẹ ibaraẹnisọrọ beere fun lọwọ NCC, ṣugbọn ajọ naa fẹnu ko pẹlu ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ si ida 50%.

Afikun owo ipe lori foonu, atẹjiṣẹ ati data pẹlu ida 50% ko le sẹnu ire fun araalu pẹlu ọwọngogo nnkan to gbode lorilẹede Naijiria.

Akọṣẹmọṣẹ kan nipa eti ibaraẹnisọrọ, Ọgbẹni Mohammed Bashir, ṣalaye pe Naijiria wa lara awọn orilẹede ti araalu ti san owo ipe ati data to kere julọ nilẹ Afirika.

Amọ, Bashir sọ pe akoko ti nnkan ko rọgbọ fun ọpọ Naijiria ni akoko yii ti ajọ NCC kede afikun owo ipe ati fifi atẹjiṣẹ ranṣẹ lori foonu ati owo data.

Aworan obinrin to mu foonu lọwọ

Oríṣun àwòrán, Gloworld/X

''Ipe ori foonu tawọn eeyan n lo N11 fun tẹlẹ yoo di N16.50''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipe ori foonu tawọn eeyan n lo N11 fun tẹlẹ yoo di N16.50 pẹlu afikun owo tariifu ti ajọ NCC kede bayii.

Atẹjiṣẹ tawọn eeyan n lo N4 lati fi ranṣẹ lori foonu tẹlẹ yoo di nnkan ti wọn n lo N6 lati fi ranṣẹ bayii.

Bakan naa, data giigi kan tawọn eeyan n fi N1000 ra tẹlẹ yoo di N1,500 bayii pẹlu afikun owo tariifu ti ajọ NCC kede.

Ohun tawọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto ibaraẹnisọrọ ṣalaye ni pe alekun ko ba owo tariifu ni Naijiria fun bi ọdun mẹwaa bayii.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn nnkan tawọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilo lati ri awọn onibaara wọn n pe lori foonu gaara, fi atẹjiṣẹ ranṣẹ ati ṣe awọn nnkan mii ti gbowo lori.

Ọga agba ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ Airtel, Dinesh Balsingh, sọ pe afikun owo tariifu tawọn onibaara n san sẹ pataki ti wọn ba fẹ maa tẹsiwaju lati maa gbadun lilo foonu wọn fun ohun ti wọn ba fẹ.

Ọgbẹni Balsingh ṣalaye pe alekun ida 300% lo ba owo tawọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ fi n ṣiṣẹ laarin ọdun meji pere.

Bakan naa ni o tun sọ pe bi owo Naira ko ti ra nnkan kan mọ naa wa lara awọn nnkan to ṣakoba fun awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ.

Ọga ileeṣẹ Airtel fikun ọrọ rẹ pe owo lita kan epo disu tawọn n lo fun ẹrọ amunawa ti lọ soke lati N230 si N1,000.

Ti ẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ MTN ati Airtel kede pe awọn jẹ gbese nitori bi awọn nnkan ti wọn fi n ṣiṣẹ ṣe gbowo lori .

MTN kede pe awọn padanu owo ti ko din ni ₦514.9bn laarin oṣu mẹsan an akọkọ ninu ọdun 2024, nigba ti Airtel padanu $89m lọdun 2023.

Awọn onibaara pariwo lori afikun tariifu ori ipe ati data

Ẹwẹ, lati igba ti ajọ NCC ti kede afikun ida 50% owo tariifu ori ipe ati data lọpọ onibaara ti n fi aidunnu wọn han.

Funmi Adejumo to jẹ oniṣowo niluu Eko sọ pe ''gbogbo igba ni wọn maa n sọ fun wa pe Naijiria lawọn eeyan ti n sanwo to kere julọ lori ipe, atẹjiṣẹ ati data nilẹ Afirika.

Amọ, ki ni eyi tumọ si nigba tawọn eeyan ko ba lagbara ra data ọhun mọ?

Lai ṣe ani ani, afikun owo tariifu yii yoo mu aye le sii fun ọpọ ọmọ Naijiria.

Ṣugbọn oninmọ nipa ọrọ aje, Aliyu Ilias, sọ pe ko si bi awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ sẹ fẹ tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ ti wọn ko ba fowo kun owo tariifu ori ipe, atẹjiṣẹ ati data.

Akọsilẹ kan ti ajọ ITU to n ri si eto ibaraẹnisọrọ lagbaaye lọdun 2023 sọ pe $2.35 lawọn eeyan n ra data giigi meji (2GB) ni Naijiria, eyi ti wọn n ra n ni $2.66 lorilẹede Ghana, $2.92 ni Kenya, ati $7.98 lorilẹede South Africa.