EFCC fẹ́ lu ọkọ̀ tó lé ní 800 ní gbàǹjo, wo bí o ṣe lè mú tìrẹ níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, efcc
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti kede pe oun fẹ lu ọkọ to le lẹgbẹrin ni gbanjo.
Iroyin ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa ni eyii to gba lọwọ awọn onijibiti.
EFCC ni itakun ayelujara ni awọn eeyan yoo ti lanfani lati dundura lori awọn ọkọ naa.
Ajọ ọhun kede loju opo X rẹ pe oun n ṣe eyii ni ibamu pẹlu ofin to rọ mọ bo ṣe n ṣiṣe, eyii ti wọn gbe kalẹ lọdun 2004, 2007 ati 2022.
EFCC gbẹsẹle awọn ọkọ naa lasiko to n ṣe iwadii awọn afurasi onijibiti.
Wọn ni ki gbogbo araalu to ba nifẹ si ati ra lara awọn ọkọ naa lọ si awọn oju opo ti wọn kede lati dunadura lori eyikeyi ti wọn ba n fẹ ninu rẹ.
Agbẹnusọ ajọ naa, Dele Oyewale sọ pe awọn ko ni ṣe ojuṣaju ninu tita awọn ọkọ ọhun, awọn yoo si tẹle ofin to rọ mọ tita rẹ.
Gẹgẹ bii ọrọ EFCC, ẹni to ba gbe owo to pọ ju sori ọkọ ninu gbogbo awọn to n dunadura ni ọkọ naa yoo jẹ tirẹ.
Ọjọ mẹta pere ni ẹni to ba bori idunadura ni lati san owo ọkọ to ba fẹ ra lati oju opo Remita Retrieval Reference (RRR).
Nigba ti BBC kan si oju opo ti wọn ti fẹ maa ta awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa, a ri pe awọn ̣ọkọ diẹ ti wa lawọn oju opo kan, bẹẹ ni ko tii si ọkọ kankan lawọn oju opo mii.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti EFC yoo lu awọn dukia awọn afurasi onijibiti ni gbanjo.
Awọn eeyan kan si ti sọ pe magomgo maa n waye lọpọ igba ti wọn ba n lu dukia ni gbanjo nitori ara wọn ni wọn maa n ta awọn ọkọ naa fun.

Oríṣun àwòrán, Screenshot















