Oriyomi padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí iléẹjọ́ gba béèlì rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ohun tó sọ rèé

Aworan Oriyomi Hamzat

Oríṣun àwòrán, Agidigbo FM/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja agbohunafẹfẹ n ni, Oriyọmi Hamzat, ti pada sẹnu iṣẹ lẹyin ti ile ẹjọ gba beeli rẹ lọgba ẹwọn lori ọrọ awọn ọmọde marundinlogoji to ku nibi apejẹ ti Olori Ooni tẹlẹ, Naomi ṣagbatẹru rẹ niluu Ibadan.

Ni ọjọ Aje ogunjọ oṣu Kinni ọdun yii ni Ọgbẹni Hamzat pada sẹnu iṣẹ ti awọn oṣiṣẹ rẹ si to siwaju ọfiisi ileeṣẹ redio Agidigbo lati ki i kaabọ.

Gbogbo awọn oṣiṣẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio naa ni Oriyomi ki lọkọọkan kari ki o to bẹrẹ si ni sọrọ.

Ṣaaju ki Oriyomi to sọrọ ni pasitọ kan to n ṣiṣẹ ni ileeṣẹ redio Agidigbo kọkọ bu adura julẹ lori Oriyomi.

Pasitọ naa gbadura fun aabo to peye fun Oriyomi bi o ti pada sẹnu iṣẹ, bakan naa lo tun gbadura fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio naa.

Alfa kan toun naa wa lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio Agidigbo ṣe adura fun Oriyomi, alfa naa gbadura fun aabo fun Oriyomi.

Ninu ọrọ rẹ, Oriyomi kọkọ ki gbogbo awọn oṣiṣẹ rẹ ku ọdun, o ki wọn ku iyedun.

''Mo dupẹ pupọ lọwọ yin, mo mọ riri yin gan an, ẹ ku idile mu, ẹ ku idi odi mu, ẹ si ku ifọwọsowọpọ.

A ti n gbadun ara wa ṣaaju akoko yii, lagbara Ọlọrun a o tun maa gbadun ara wa si ni.

Ẹ ṣe ti ẹ jẹ ki n ba yin nile, mo dupẹ pupọ lọwọ yin,'' Oriyomi lo sọ bẹẹ.

Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ naa ni oun ko tii le sọrọ pupọ bayii pẹlu gbogbo nnkan to ti ṣẹlẹ.

O ni oun kan fẹ sọ fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio Agidigbo pe oun naa ti wọ iṣẹ pada ni.

Oriyomi tun lo anfaani naa lati kede ọga agba tuntun fun ileeṣẹ redio Agidigbo.

O fi igboya sọ fawọn oṣiṣẹ rẹ wi pe ibi ti Agidigbo n lọ, awọn maa de ibẹ laipẹ.

Ile ẹjọ pasẹ fun Oriyomi pe ko gbọdọ sọ ohun ti oju rẹ ri lori awọn eto rẹ lori afẹfẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro naa ni adajọ fun Oriyomi ni awọn gbedeke kan lati tẹle, ko to di pe wọn yoo gba beeli rẹ.

"Lara awọn gbedeke ti adajọ fi lelẹ ni pe Oriyomi gbọdọ fi oniduro meji silẹ, ti awọn mejeeji si n gbe nilu Ibadan.

O ni awọn oniduro mejeeji gbọdọ fi iwe asẹ irinna wọn silẹ, ki wọn si tọwọ bọ iwe lati mu afurasi naa wa sile ẹjọ nigbakuugba to ba yẹ lasiko ti igbẹjọ naa ba n lọ lọwọ."

Amofin Sobaloju ni ile ẹjọ naa tun pasẹ fun Oriyomi pe ko gbọdọ sọ ohunkohun ti oju rẹ ri lori isẹlẹ yii lori awọn eto rẹ lori afẹfẹ.

Bakan naa nile ẹjọ tun fi ofin de Oriyomi lati mase sọrọ nipa igbẹjọ to n lọ lọwọ naa lori afẹfẹ titi ti ẹjọ yoo fi pari.

"Ile ẹjọ ni kawọn oniduro Oriyomi mejeeji tun tọwọ bọ iwe adehun pe awọn yoo san miliọnu mẹwa ẹnikọọkan bi afurasi ọhun ba salọ."

Nigba to n sọrọ lori ẹsun onikoko mejidinlogun tuntun ti ijọba ipinlẹ Oyo fi kan awọn afurasi mejeeji, amofin Sobaloju ni awọn ẹsun tuntun naa lagbara to ẹsun mẹrin akọkọ tijọba fi kan wọn.