Wó kókó ọ̀rọ̀ tí Donald Trump sọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìbúrawọlé fún un

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, kete ti wọn se iburawọle fun ba awọn araalu Amẹrika ati awọn olori ilu naa sọrọ pe igba rẹ yoo san orilẹede Amẹrika.
Lara awọn to wa nibi iburawọle naa ni Aarẹ ana, Joe Biden ati Igbakeji aarẹ to jẹ oludije fun ipo aarẹ, Kamala Harris pẹlu awọn aarẹ tẹlẹ ri ni Amẹrika.
Trump saaju ọrọ rẹ pẹlu ọrọ tutu fun awọn araalu to si fi da wọn loju pe igba ọtun ti bẹrẹ lorilẹede Amẹrika.
"Igba ọtun ti bẹrẹ ni Amẹrika lati asiko yii lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Lati isin yin lọ, ilọsiwaju yoo de ba orilẹede wa.
"Ma ri pe mo fi orilẹede saaju ohun gbogbo."
Trump tun fi da awọn araalu loju pe ijọba awarawa yoo gbinlẹ, ti ijọba rẹ yoo si ri pe oun kaa araalu kun ni gbogbo ọna.
"Erongba wa ni lati sọ orilẹede Amẹrika ni orilẹede nla to ni okiki ju ti tẹlẹ lọ, ti ilọsiwaju yoo si wa ni ayika rẹ."
Aarẹ Trump ni bi oun se pada si ipo aarẹ, orilẹede Amẹrika yoo tunbọ ni agbara si ju ti tẹlẹ lọ.
Bakan naa ni Trump tun sọko ọrọ si eto iṣejọna aarẹ ana, Joe Biden lori bi awọn eeyan se n wọ orilẹede Amẹrika.
O fẹsun kan ijọba ana pe wọn da bobo awọn ọdaran ti wọn gba ọna eru wọ orilẹede Amẹrika.
Aarẹ Trump ni ki awọn araalu fọkan balẹ pe ayipada n bọ ni kiakia.
O ni igba ọtun yoo de ba eto ẹkọ ati eto ilera ni orilẹede naa
O ni idi ti mo fi wa laye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Trump sọ nipa igbiyaanju awọn eeyan kan lati sekupa lasiko eto ipolongo Ibo.
O ni kadara o ṣe yi pada, to si jẹ pe wọn ti dan an wo ju awọn aarẹ yooku lọ.
Aarẹ ni awọn eeyan kan gbiyanju lati fopin igba rẹ, ti wọn si fẹ gba ominira rẹ
O ni Ọlọrun da oun si fun idi kan to si jẹ pe o jẹ lati mu orilẹede Amẹrika ga si ni ni gbogbo ọna
Trump ni iṣejọba yoo ri pe o lo gbogbo ọna lati mu ilọsiwaju ba orilẹede Amẹrika, ti alaafia yoo si jọba fun gbogbo ẹya to wa ni ilu naa
"Ọjọ ominira ni Ogunjọ oṣu Kinni ọdun 2025 jẹ.
"Igbagbọ mi pe eto idibo ti pari yoo jẹ ti wọn yoo ma se iranti pe o jẹ eto idibo nla ninu itan orilẹede wa."
O ni gbogbo ala ati erongba orilẹede Amẹrika ni yoo wa si imusẹ lasiko iṣejọba, ti yoo si tun ga ju ti tẹlẹ lọ.
Trump pari ọrọ rẹ pẹlu pe ọja ọla lọwọ awọn araalu nitori awọn araalu ti sọrọ fun ara wọn.
"Mo duro si yin iwaju gẹgẹ bii ẹri pe ẹ ko gbọdọ gbagbọ ko le sese. Ni Amẹrika, nnkan ti wọn ba ni ko le ṣeese ni a dara si ju.
"A no ri ijakulẹ. Lati oni lọ, orilẹede Amẹrika yoo gba ominira tuntun.
"A wa la ni ọjọ ọla, igba ọtun ti bẹrẹ bayii















