‎Ìbànújẹ́ ni ikú Oluwafunlola Laisi jẹ́ sí àwa ẹbí ọkọ̀ rẹ̀ - Ẹ̀gbọ́n ọkọ̀ rẹ̀

Awọn ẹṣọ oju popo meji n gbiyanju lati gbe posi funfun sinu iho
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹsan-an, oṣu Kiini, ọdun 2025 ni oku arabinrin Oluwafunlola Laisi ti o jade laye ninu oṣu Kejila ọdun 2025 lẹyin ti ọrẹkunrin rẹ tan-an lọ sile Babalawo lati fi ṣe etutu ọla wọ kaa ilé sun.

Ni aago mẹjọ owurọ ni wọn gbe oku Oluwafunlola ati ọmọ rẹ Adesewa kuro ni ile igbokusi ti ile iwosan Fasiti ipinlẹ Osun, lati lọ sin-in ni ile ijọsin St. John Anglican Church eyi to wa lẹyin ìsọ̀ pako, agbegbe Itaolokan niluu Osogbo.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ nibi eto isinku naa, Tajudeen Dauda Laisi, ẹni to jẹ ẹgbọn si ọkọ Oluwafunlola Laisi sọ pe obinrin rere to nifẹẹ ẹbi ọkọ rẹ daadaa ni nigba to wa laye.

Tajudeen kọminu pe ọrọ iku Oluwafunlola Laisi ṣe rin jẹ ohun ibanujẹ gidigidi fun awọn ati pe ọna to gba wa jẹ ọna to ku diẹ kato fun gbogbo awọn ẹbi ọkọ rẹ.

‎O woye pe "ko si oun ti a le ṣe si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si Oluwafunlola Laisi ati ọmọ rẹ Adesewa."

‎O fi kun pe ẹkọ nla ni iku Oluwafunlola jẹ fun gbogbo eeyan paapaa awọn tọkọtaya ti wọn ko bag be papọ.

Bakan naa ni ẹni to jẹ aburo si oloogbe, ‎Patrick Adegboye sọ pe iku ẹgbọn oun jẹ adanu nla fun ẹbi awọn paapaa awọn ti awọn jẹ aburo lẹyin oloogbe naa.

O fi kun pe bi o tilẹ jẹ pe iku rẹ lọwọ kan ninu sibẹ awọn fi idajọ si ọwọ Ọlọrun.

‎‎Ninu iwaasu Oluṣọ-agutan Lekan Salami, ẹni to dari eto isinku naa, o rọ awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn akẹgbẹ oloogbe Oluwafunlola Laisi ma ṣe banujẹ mọ.

O ni ko si ẹni to mọ iru iku ti oun naa yoo ku ti ọlọjọ ba de, to ssi jẹ pe ohun to yẹ gbogbo eeyan logun julọ laye yii ni lati maa ṣe rere.

‎‎ ‎Pẹlu ibanujẹ ati omije loju ni awọn oṣiṣẹ ẹsọ alabo oju popo ṣe fi ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fun arabinrin Oluwafunlola Laisi ati ọmọ rẹ Adesewa nibi eto isinku naa.

‎‎Ọga agba awọn ẹsọ aabo oju popo FRSC ẹka ti ipinlẹ Osun, Arakunrin Leye Adegboyega wa lara awọn oṣiṣẹ FRSC to peju sibi eto isinku ọhun.

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ FRSC lati ipinlẹ Ogun ko gbẹyin lati ṣẹyẹ ikẹyin fun ara wọn to doloogbe.

Ètò ìsìnkú òṣìṣẹ́ FRSC tí wọ́n ní ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa fún ètùtù ọlà ní ìpínlẹ̀ Osun bẹ̀rẹ̀

Àtẹ̀jáde tí ẹbí fi kéde ètò ìsìnkú Funlola àti ọmọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others

Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe lọjọ Eti, ọjọ Kẹsan-an oṣu Kiini ọdun 2026 ni eto isinku oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo FRSC Arabinrin Laisi Oluwafunlola Oluwamayokun ati ọmọ rẹ Laisi Adesewa Zeenat ti wọn ni ọrẹkunrin rẹ pa fun etutu ọla yoo waye.

‎‎Ni deede aago mẹjọ owurọ ni wọn yoo gbe oku arabinrin Oluwafunlola ati ọmọ rẹ Adesewa kuro ni ile igbokusi ti ile iwosan Fasiti ipinlẹ Osun, lọ si ibi ti yoo ti fi ara lelẹ.

Ni ile ijọsin St. John Anglican Church eyi to wa lẹyin ìsọ̀ pako, to wa ni agbegbe Itaolokan niluu Osogbo, nipinlẹ Osun ni eto isinku naa ti maa waye gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi lede.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎‎Tẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni iroyin gbode lori iku arabinrin naa ati ọmọ rẹ eyi ti wọn ni ko sẹyìn bi ọrẹ rẹ kan ṣe tan-an lọ si ipinlẹ Osun lati ipinlẹ Ogun to ti n ṣiṣẹ, to si tan an lọ si ọdọ babalawo lati fi ṣe etutu ọla rẹ.

‎‎Ni ọjọ Kẹta osu Kejila ọdun 2025 ni ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun fi oju awọn afurasi to ṣe iku pa Arabinrin Oluwafunlola ati ọmọ rẹ Adesewa lede.

‎Ọjọ Aje, ọjọ Kẹtadinlogun osu Kọkànlá ọdun 2025, ni afurasi Gboyega Daramola, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Aberefa" mu awọn agbofinro lọ si ilu Esa-Odo ni ipinlẹ Osun nibi ti wọn gbe oku arabinrin Funmilola Oluwamayokun, ẹni ọdun mejidinlogoji pamọ si.

Nigba ti wọn fi maa debẹ, ko si awọn ẹya ara bii ọyan, ọwọ mejeeji, oju ara atawon mii lara arabinrin naa.

‎‎Lẹyin iwadii ni Ile-iṣẹ ọlọpaa gbe oku arabinrin naa lọ si Ile igbokusi ti Ile iwosan Fasiti ipinlẹ Osun.

‎‎Lati igba naa ni oku Arabinrin Oluwafunlola ati ọmọ rẹ Adesewa ti wa nile igbokusi titi di asiko yii ti wọn fẹ sin-in.

‎‎ Oluwafunlola jẹ ọga lẹnu iṣẹ ẹsọ ọkọ oju popo (FRSC) ti ijọba apapọ, ẹka ti ipinlẹ Ogun ko to jade laye.