Àjọ NERC kéde pé Togo, Niger àti Benin ń jẹ Naijiria ní 25bn owó iná mọ̀nàmọ́ná

Aworan agbara ina mọnamọna

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC) to n ri si ina mọnamọna lorilẹede yii ti sọ pe orilẹede Togo, Niger ati Benin n jẹ Naijiria ni $17.8m, eyi to le ni 25bn ti a ba ṣẹ ẹ si Naira lasiko iroyin yii.

NERC sọ pe awọn orilẹeede naa jẹ Naijiria lowo yii nipasẹ ipese ina fun wọn, eyi to ni adehun ati ajọsọ ninu.

Ninu abajade ajọ NERC, ti ipele kẹta odun 2025 ni wọn ti fidi ẹ mulẹ, pe $18.69m lo yẹ kawọn orilẹede mẹta naa san laaarin asiko ọhun, ṣugbọn $7.125m ni wọn san, o si ku gbese $11.56m.

Orukọ awon ileeṣẹ orilẹede mẹta naa bi NERC ṣe kede ẹ ni: Compagnie Énergie Électrique du Togo, Société Béninoise d'Énergie Électrique of the Republic of Benin, ati Société Nigérienne d'Électricité of the Republic of Niger.

"Awọn onibaara wa mẹta lati ilẹ okeere ti GenCos n fun ni ina ni NESI san $7.12 million, dipo $18.69 to wa ninu adehun ti a jọ ṣe fun abala 2025/Q3, eyi to tumọ si pe 38.09% ni wọn san."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade NERC naa ṣalaye.

Wọn fi kun un pe awọn onibaara yii san N3.19 billion, dipo N3.64 billion to yẹ ki wọn san gẹgẹ bi adehun abala Q3 2025.

Ajọ NERC sọ pe ileeṣẹ Ajaokuta Steel Co. Ltd ati agbegbe to wa ko tilẹ sanwo kankan ninu N1.03 billion ti Nigerian Bulk Electricity Trading (NBET) Plc ni ki wọn san ati N100 million adehun to wa fun abala yii.

NERC ni oun ti ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ yii fawọn ẹka to yẹ ko gbọ nipa rẹ nileeṣẹ ijọba apapọ.

Amọ ọpọ araalu Naijiria lo n kọminu si ọrọ yii, wọn ni ina meloo ni Naiiria gan-an ri lo, ko too maa pinna sita.