Kí nídìí tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers fi bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ Gómìnà Fubara nípò?

Oríṣun àwòrán, Fubara/ Facebook
Níṣe ni ọ̀rọ̀ òṣèlú ìpínlẹ̀ Rivers tún ti gba ọ̀nà míì yọ báwọn aṣòfin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ṣe ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ Gómìnà Siminalayi Fubara àti igbákejì rẹ̀, Ngozi Odu nípò.
Níbi ìjòkòó ilé aṣòfin tó wáyé lọ́jọ́ Kẹjọ, oṣù Kìíní tí olórí ilé aṣòfin, Martin Amaewhule darí rẹ̀ ni ìgbésẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀.
Olórí ọmọ ilé tó pọ̀ jùlọ, Major Jack ló ka àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Fubara jáde.
Nígbà tó ń fìdí ìgbésẹ̀ náà múlẹ̀ pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà, Jack ka àwọn ìwà aṣemáṣe mẹ́sàn-án tó ní ó lòdì sí òfin.
Lára àwọn ẹ̀sùn tó kà ni:
- Wíwó ilé aṣòfin
- Níná àbá ìsúná láì gbàṣẹ nílé aṣòfin
- Kíkó owó tó wà fún àjọ tó ń rí ọ̀rọ̀ ilé aṣòfin dání
- Kíkọ̀ láti tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà nípa ètò ìsúná ilé aaṣòfin
- Àti fífi àwọn èèyàn sípò ìjọba láì í àyẹ̀wò àti ìbuwọ́lù ilé aṣòfin.
Àwọn aṣòfin mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ló ti buwọ́lu àbá náà lẹ́yìn tí Major Jack kà á sétí ilé.
Olórí ilé aṣòfin ní àwọn máa fi àbá náà ránṣẹ́ sí Gómìnà Fubara láàárín ọjọ́ méje gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni igbákejì olórí ilé, Linda Stewart náà ka àwọn ẹ̀sùn sí igbákjì gómìnà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ngozi Odu lẹ́sẹ̀.
Lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn ni:
- Níná owó ìlú ní ìnákúnàá
- Àìjẹ́ kí ilé aṣòfin ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe yẹ lábẹ́ òfin
- Lílẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú gómìnà láti fi àwọn èèyàn tí kò tọ́ sípò láì sí àṣẹ ilé aṣòfin
- Ó kàn sáwọn kan láti buwọ́lu àbá ìsúná dípò gbígba àṣẹ láti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers.
- Gbígbẹ́sẹ̀ lé owó oṣù àti àjẹmọ́nú àwọn òṣìṣẹ́ ilé aṣòfin àti àjọ tó ń rí sí ètò ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers.
Olórí ilé aṣòfin, Martin Amaewhule sọ pé òun wòye pé láti ìgbà tí Ààrẹ Bola Tinubu ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìkéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Gómìnà Fubara kò gbé àbá ìsúná síwájú ilé náà, tó sì ń jẹ́ ìyàlẹ́nu fún òun bí wọ́n ṣe ń náwó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé aṣòfin àgbà tó wà ní ìlú Abuja buwọ́lu àbá ìsúná fún ẹni tó ṣàkóso ìpínlẹ̀ náà fún mẹ́fà tí gómìnà àti igbákejì rẹ̀ lọ rọ́kún nílé.
Bákan náà ló tún fẹ̀fsùn kàn pé Fubara yan àwọn kan sípò láì gbàṣẹ àti ìbuwọ́lù nílé aṣòfin.
Láìpẹ́ yìí ni Gómìnà Fubara yan àwọn olùbánidámọ̀ràn, tó sì tún ṣe àtúntò ìgbìmọ̀ aláṣẹ rẹ̀ níbi tó ti yan ẹni tó jẹ́ Kọmiṣánnà féré ìdárayà tẹ́lẹ̀, Christopher Green sípò agbẹjọ́rò àgbà fún ìpínlẹ̀ náà.
Bákan náà ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ gómìnà buwọ́lu àbá isúná 2026 ṣáájú ilé aṣòfin bí Gómìnà Fubara ṣe òun ń dúró de kí wọ́n parí ilé aṣòfin tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ kí òun tó gbé àbá ìsúná síwájú àwọn aṣòfin náà.
Ìrètí wà fún gómìnà láti fèsì sí àwọn ẹ̀sùn táwọn aṣòfin fi kàn án náà tí wọ́n bá ti gbé síwájú rẹ̀ láàárín ọjọ́ méje.
Ìbáṣepọ̀ láàárín Wike àti Fubara
Ìgbésẹ̀ láti yọ Gómìnà Fubara nípò yìí ló ń wáyé lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣàfihàn pé àárín Gómìnà Fubara àti Mínísítà fọ́rọ̀ Abuja, Nyesom Wike kò gún mọ́.
Ṣáájú ni Wike ti ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ Rivers fún òpin ọdún, táwọn ọ̀rọ̀ tó sì sọ níbẹ̀ jọ pé àárín àti Fubara kò gún mọ́.
Ó sọ pé mímọ oore àti ìwà gbangba làṣáta ni ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ àjọṣepọ̀ tó dán nídìí òṣèlú ṣùgbọ́n tó ní aláìmoore ni Fubara àti pé kò tẹ́lẹ̀ gbogbo ohun táwọn fẹnukò lé lórí kí wọ́n tó parí ìjà.
Wike ní òun ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ri pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP ṣiṣẹ́ papọ̀ níbi ètò ìdìbò ọdún 2027 láti le ri pé àjọṣepọ̀ náà ló máa sọ ẹni tó máa













