Ìjọba mi yóò rí i dájú pé irú ìkọlù yíì kò ṣẹlẹ̀ mọ́- Gómìnà Seyi Makinde

Aworan Gomina Seyi Makinde to n sọrọ pẹlu ẹrọ gbohun-gbohun, abala kan to jona nigbo Oba Oloka ati awon ọlọpaa to ṣabẹwo sibudo naa.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Latari ikọlu awọn agbebọn si igbo ọba ipinlẹ Oyo lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, nibi ti wọn ti pa ọdẹ aṣogbo marun-un, Gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde, ti ni iru rẹ ko ni i waye mọ.

Ninu ọrọ ti Makinde fi soju opo X rẹ lanaa Ọjọruu lo ti fidi ikọlu to waye ni abule Oloka naa mulẹ.

O ba awọn to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ wọn naa kan kẹdun pẹlu.

Gomina Makinde ṣalaye pe iwadii awọn ẹṣọ alaabo fi han, pe awọn agbesunmọmi to ti ẹnu ibode ibomiran wa lo ṣe iṣẹ ibi naa.

"Awọn ẹṣọ alaabo ti bẹrẹ iṣẹ lati yanju ikọlu yii, ki wọn si beere fun ifọwọsowọpọ awọn olugbe agbegbe naa bi wọn ṣe n tọpinpin.

"Ẹ jẹ ki n rọ awọn olugbe Oyo, paapaa awọn to n gbe nijọba ibilẹ Oriire atawọn mi-in loju ọna ẹnu ibode, lati farabalẹ, awọn ẹṣọ alaabo ti da alaafia pada si agbegbe naa.

"Ijọba mi yoo ri i daju pe a ṣe ohun gbogbo lati dena iru ikọlu yii ko ma ṣe waye mọ."

Bẹẹ ni Gomina Seyi Makinde wi

Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo ṣabẹwo sibi ikọlu naa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Femi Haruna, ti ṣabẹwo sibudo ikọlu naa pẹlu ikọ rẹ.

Ọga ọlọpaa Oyo to ba awọn olori agbegbe Oloka sọrọ, ṣalaye pe igbo ọba gan-an ni awọn agbesunmọmi naa doju kọ, lodi si ohun ti awon kan n sọ pe ilu ni wọn tori rẹ wa.

Haruna sọ pe bi ikọlu naa ṣe to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni awọn ti ran awọn ẹṣọ lọ sibẹ, ko ma baa di ohun ti yoo ran kari ilu.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Oyo, DSP Ayanlade Olayinka fi sita lanaa ọjọ Iṣẹgun, lo fi ṣalaye irin ajo CP Haruna.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ọga ọlọpaa ẹkun Ikoyi atawọn ikọ alaabo miran ni wọn lọ si Oloka lati da aabo bo agbegbe naa, ki wọn si finmu finlẹ lati ri awon ẹri kan tabi meji mu.

Nipa oku awọn aṣọgbo marun-un naa, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ti fi tọwọtọwọ ṣe wọn lọjọ si aaye igbokuusi.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti wa paṣẹ afikun awọn ẹṣọ alaabo si agbegbe naa, pẹlu gbogbo ohun eelo ti wọn yoo nilo.

Gbogbo ipa lo ni ki wọn sa lati mu awọn to ṣiṣẹ ibi yii, iwadii si ti bẹrẹ pẹrẹu bi wọn ṣe sọ, eyi to n tọka bi ọwọ yoo ṣe ba awọn amookunṣika naa.

Bawo ni ikọlu ọhun ṣe waye gan-an?

Gẹgẹ bi atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa Oyo ṣe wi, iwadii fi han pe awọn agbebọn naa to mejila ti wọn yade lati awọn igbo to wa nitosi.

Bi wọn ti de ni wọn ṣina ibọn bole si ọfiisi awọn aṣọgbo ọba ti wọn n pe ni Rangers' Office, bi wọn ti yinbọn naa tan ni wọn si sa lọ.

Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti ni oun duro digbi lati da aabo bo awọn eeyan ibẹ ati dukia wọn lọwọ ikọlu kaakiri ilu naa.

Wọn fi da araalu loju pe gbogbo igbesẹ to yẹ ni awọn n gbe lati tete mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa, ti wọn yoo si foju bale ẹjọ.

Wọn ni ki gbogbo ara Oyo fi ọkan balẹ, bi wọn ba nilo lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa ibẹ ni pajawiri, nọmba ti wọn ko ni i fowo pe yii ni wọn ni ki wọn pe: 615.

To ba si ṣe yara olu ileeṣẹ ọlọpaa Oyo ni, eyi ni wọn yoo pe bi atẹjade naa ṣe sọ: 08081768614 & 07055495413.

Awọn agbébọn ṣèkọlù sáwọn aṣọ́gbó ọba, pa èèyàn mẹ́rin nípìnlẹ̀ Oyo

Àwọn agbébọn tó gbé ìbọn dání, fi ọta ìbọn kọ́rùn, wọ́n fi aṣọ bo gbogbo ojú wọn

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn agbebon ṣe ikọlu si ọfiisi ajọ asọgbo ọba to wa ni agbegbe Oloka, ijọba ibilẹ Orire nipinlẹ Ọyọ.

‎‎Ikolu naa to waye ni nnkan bii aago mẹsan alẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹfa, oṣu Kiini, ọdun 2026 ṣokunfa iku aṣọgbo mẹrin, ti ẹnikan si w ani ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun

Iroyin ni awọn agbebọn to ṣekọlu sawọn aṣọgbo naa ko gbogbo ìbọn ti wọn n lo lọ.

‎‎‎Atẹjade kan ti agbenuso ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fi lede,Ayanlade Olayinka fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ṣalaye pe ile iṣe ọlọpaa ati awọn ajọ to niṣe pẹlu aabo ilu ni wọn ti wa ninu igbo ọba ọhun lati ṣawari awọn agbebon to ṣekọlu ọhun.

‎Olayinka tesiwaju pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Femi Haruna pẹlu awọn olori ileeṣẹ aabo to wa nipinlẹ Ọyọ ti n lọ si agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

O ni igbesẹ yii lo n waye lati ri wi pe alaafia pada si agbegbe naa lojuna ati ri daju pe aabo wa fun gbogbo awọn eeyan ati dukia lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Atẹjade naa wa rọ awọn ara ilu Oloka lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ki ọwọ le tete tẹ awọn afurasi agbebọn naa.

‎ Ọkan lara olugbe agbegbe naa to ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye wi pe mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ asọgbo ọba lọ jade laye, ti ẹnikan yooku si wa ni ile iwosan nibi to ti n gba itọju.

‎O sọ pe gbogbo ilu naa lo ti dahoro, ti gbogbo awọn araalu ti sa kuro nile wọn tan.

O fi kun pe to fi mọ Baalẹ ilu naa lo ti kuro ninu ilu.

Ikọlu yii ni yoo jẹ akọkọ iru rẹ ni agbegbe yìí.