Ṣé lóòótọ́ ni pé agbébọn làwọn èèyàn mẹ́fà táwọn ọmọ ogun mú ní ìpínlẹ̀ Edo pẹ̀lú ọkọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ Kwara?

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti tu awọn fijilanté mẹ́fà ti awọn ọmọ ogun Naijiria mu ni ipinlẹ Edo lọdun to kọja silẹ ni alaafia.
Itusilẹ naa waye lẹyin ti ileeṣẹ ologun Naijiria tẹka ipinlẹ Kwara ti kọkọ jọwọ awọn fijilante ọhun fun awọn ọlọpaa fun iwadii lẹyin ti wọn nawọ gan wọn, pẹlu ẹsun pe agbeṣumọmi ni wọn.
Eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi fi lede lọjọ Kẹfa, oṣù Kìíní, ọdun 2026.
Atẹjade naa sọ pe "ni ọjọ Kọkanlelọgbọn, osu Kejila ọdun 2025 ni ileeṣẹ ọlọpaa Kwara gba awọn fijilante mẹfa ti awọn ọmọ ogun mu ni opopona Auchi–Ikpeshi ni ijọba ibilẹ Akoko-Edo ni Ipinlẹ Edo.
"Awọn fijilante naa ti wọn n rin irinajo ninu ọkọ to jẹ ti ijọba ibilẹ Ifelodun ni Ipinlẹ Kwara ni ọga agba awọn soja tẹka Sobi ni Ilorin, Brigadier General N.N. Rume, ti saaju jọwọ fun awọn ọlọpaa fun iwadii to peye.
"Lẹyin iwadii, o han gbangba pe awọn mẹfa naa jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ fijilante ti wọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ojulowo ajọ awọn ọmọ ogun lati gbogun ti iwa awọn agbebọn ati awọn iwa ibajẹ mii lawujọ.
"Lẹyin-o-rẹyìn ti a rii pe wọn kii se onisẹ ibi, a ti jọwọ wọn fun awọn adari wọn"
Atẹjade naa fi kun pe Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, CP Ojo Adekimi sọ pe ajọ naa yoo maa tẹsiwaju lati maa sisẹ papọ pẹlu awọn ọmọ ogun mii to fi mọ awọn ikọ ologun abẹle.
O wa rọ gbogbo ikọ ki wọn tẹsiwaju lati maa sisẹ wọn ni ibamu pẹlu ofin.
O fi kun-un pe ki gbogbo eniyan lọ fọkan balẹ nitori ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kuna lati maa da aabo bo ẹmi ati dukia araalu.
Ki lo ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Ninu osu Kejila, ọdun to kọja ni fọnran kan gba ori ayelujara eyi to ṣafihan awọn eeyan mẹfa kan ti wọn dọbalẹ, tawọn kan n beere nnkan lọwọ wọn.
Ninu fidio naa ni awọn eniyan yii ti n jẹwọ pe "ijọba Ilorin" lo fun awọn ni ọkọ lẹyin ti ijọba apaapọ gbe ibọn fun awọn nigba ti awọn Ologun n beere ọrọ lọwọ wọn.
Ọkọ naa ni wọn kọ orukọ ijọba ibilẹ Ifẹlodun ni Ipinlẹ Kwara si lara.
Ati igba naa ni awuyewuye ti n lọ lori iṣẹlẹ naa ti awọn eniyan si n fun-un ni orisirisi itumọ.
Ohun tawọn eeyan kan n sọ nigba naa ni pe lara awọn agbebọn to n da ipinlẹ Kwara laamu lawọn eeyan naa, ti ọwọ awọn ọmọ ogun si tẹ wọn ni ipinlẹ Edo lasiko ti wọn n sa lọ.
Amọ ileeeṣẹ ọlọpaa ti wa fidi rẹ mulẹ bayii pe awọn eeyan naa kii ṣe agbebọn bikoṣe awọn fijilante ti wọn n ba ijọba ṣiṣẹ lojuna ati fopin si ijinigbe to n ba ipinlẹ naa finra.
Saaju iṣẹlẹ naa ni ijọba Ifẹlodun ti fi lede pe awọn n wa ọkọ awọn kan ti awọn gbe fun ikọ fijilante lati koju ijinigbe sugbọn ti wọn kọ lati da a pada nigba ti isẹ wọn pari pẹlu awọn.
Ǹjẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun ti rí ọkọ̀ wọn gbà padà?
BBC News Yoruba kan si agbẹnusọ fun alaga Ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ọgbẹni Jimba lati mọ boya wọn ti da ọkọ wọn pada.
O sọ pe oun yoo kan si ọga oun lori rẹ koun si jabọ fun wa, sugbọn titi a fi ko iroyin yii jọ tan, a o gbọ nnkankan latọdọ rẹ.
Ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Wayi o, ohun ti awọn eniyan kan to bẹbẹ ki a fi orukọ bo awọn lasiri ba BBC News sọ ni pe, lootọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti da awọn eniyan naa lare pe wọn kii se agbebọn.
Sugbọn ki lode ti wọn o da ọkọ ijọba ibilẹ Ifelodun pada lẹyin ti iṣẹ wọn pari pẹlu wọn?
Ibere keji ni pe, iru iṣẹ wo ni wọn lọ fi ọkọ naa se ni Ipinlẹ Edo kọwọ awọn soja to tẹ wọn?















