Kí ló ń fa fàákája láàrin Wike àti akọ̀wé APC, tí Sẹ́nẹ́tọ̀ Basiru fi ní kí Wike kọ̀wé fipò mínísítà sílẹ̀? Àlàyé rèé

Gomina Similinayi Fubara ipinlẹ Rivers wọ aṣọ funfun, akọwe ẹgbẹ APC wọ aṣọ buluu nigba ti Nyesom Wike wọ aṣọ funfun bakan naa

Oríṣun àwòrán, Senator Ajibola Basiru/Facebook/Nyesom Wike/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awuyewuye si n lọ lori faakaja to n ṣẹlẹ laarin Minisita Abuja, Nyesom Wike ati akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnẹtọ Ajibola Basiru pẹlu bi Sẹnẹtọ Basiru ti kilọ fun Wike wi pe ko ye dasi ọrọ ẹgbẹ APC.

Sẹnẹtọ Basiru sọ pe ki Wike kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii minisita ti ko ba ni le gboju kuro lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Basiru fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti o fi sita lanaa ọjọ Aje ọjọ karun un oṣu Kinni.

Sẹnẹtọ Basiru ni ọrọ ti Wike sọ tabuku oun ati ọfiisi oun gẹgẹ bii akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC, tori nnkan toun sọ wi pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ igbimọ amuṣẹya NWC APC gbọdọ fawọn gomina to wa nipo lọwọ ni ọwọ to tọ si wọn.

Akọwe APC ni iyalẹnu lo jẹ foun pe ọrọ toun sọ yii le bi ẹnikẹni ninu debi wi pe wọn a maa sọrọ kobakungbe soun papaa julọ ẹni to jẹ ọmọ igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ.

Basiru duro lori ẹsẹ rẹ pe ko yẹ ki Wike si wa ninu igbimọ alaṣẹ ijọba Aarẹ Bola Tinubu niwọn igba to n da aawọ silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni ko yẹ ki Wike lanfaani lati maa lo ọfiisi rẹ gẹgẹ bi minisita lati maa da wahala silẹ ninu ẹgbẹ APC.

''Nnkan to mu iyi wa to yẹ ki Wike se ni pe ko kọwe fipo minisita to wa silẹ,'' Sẹnẹtọ Basiru lo sọ bẹẹ.

Sẹnẹtọ Basiru ni Wike ko lẹtọọ lati maa dasi ọrọ to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC tori pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ki ni Wike sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni Wike ti kilọ fun Sẹnẹtọ Basiru wi pe ko maa dasi ọrọ oṣelu ipinlẹ Rivers, bakan naa lo ni ko ye sọ ọrọ kobakungbe nipa ipinlẹ Rivers mọ.

Wike sọrọ ikilọ yii lanaa ọjọ Aje lasiko to ṣabẹwo ikini si ijọba ibilẹ Oyigbo nipinlẹ Rivers.

Nibi eto naa ni Wike ti sọ pe ọpọ oloṣelu loju wọn wa lara N600bn to wa lapo ijọba ipinlẹ Rivers, o ni eyi gan an lo jẹ ki wọn maa sọ nnkan to wu wọn nipinlẹ naa.

Wike sọrọ yii lẹyin ti igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu APC lẹkun guusu-guusu (South-South), Victor Giadom ṣapejuwe Gomina Siminalayi Fubara gẹgẹ bii gomina ti ko lẹnu lasiko ti Wike ṣabẹwo si ijọba ibilẹ Khana ati Gokana nipinlẹ Rivers.

A gbọ wi pe Giadom ni Gomina Fubara ko le wọle saa keji ti ko ba fi ti Wike ṣe.

Ọrọ ti Giadom sọ yii ni Sẹnẹtọ Basiru ṣapejuwe gẹgẹ bi eyi to kudiẹ kaato.

Sẹnẹtọ Basiru sọ pe ko yẹ ki ẹnikẹni tabuku ipo gomina, koda ti iru ẹni bẹẹ ba tiẹ ni ija pẹlu gomina gan an.

Akọwe agba APC sọ loju opo Facebook rẹ pe nnkan to buru jai ni ki ọmọ ẹgbẹ igbimọ amuṣẹya NWC maa ṣapejuwe gomina ipinlẹ Rivers bii gomina ti ko lẹnu.

Basiru ni ''Ọfiisi to ga ni ọfiisi gomina, awọn eeyan si gbọdọ bu ọla fun ẹnikẹni to ba si wa nibẹ.''

Amọ, Wike da a pada fun Sẹnẹtọ Basiru wi pe ko ma dasi ọrọ oṣelu ipinlẹ Rivers.

Wike ni ki Basiru kẹkọọ lara awọn to ti dasi ọrọ oṣelu ipinlẹ Rivers tẹlẹ pẹlu nnkan ti oju wọn ri.

''Ẹ jẹ ki n sọ fawọn to n wa si ipinlẹ Rivers tori pe ẹ ti gbọ pe a ni N600bn.

Ẹ n wa sibi lati gba ninu owo naa, bakan naa lẹ n lanu gbua lati sọ nnkan to wu yin.

Mo fẹ ki ẹ lọ sọrọ yii fun akọwe gbogbogbo APC wi pe ki o fi ipinlẹ Rivers silẹ.

Ma ro wi pe a gọ pẹlu bi a ti ṣatilẹyin fun aarẹ, o ni lati ṣọra.

Ẹyin n gbadun lonii nipinlẹ Osun, ẹ o mawọn to ti ṣiṣẹ sẹyin.

O n sọ nnkan to wu ọ nipa ipinlẹ Rivers, faramọ nnkan ti o ba ri nibẹ ni o,'' Wike lo sọ bẹẹ.

Sẹnẹtọ Basiru da a pada fun Wike

Ninu esi rẹ, Sẹnẹtọ Basiru sọ pe ojuṣe oun ni lati daabo bo ẹgbẹ oṣelu APC ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa.

Basiru ni oun o ṣe ayọjuran pẹlu bi oun ṣe dasi ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Rivers.

''Gẹgẹ bii akọwe agba ẹgbẹ APC, kii ṣe ipinlẹ Osun to jẹ ipinlẹ mi nikan ni mo ti n ṣiṣẹ.''

Lori ọrọ ti Wike sọ pe nitori N600bn to wa lapo ijọba ipinlẹ Rivers lọpọ oloṣelu ṣe n wa si ipinlẹ naa, Basiru ni ọrọ naa ko lẹsẹ nlẹ; o ni ọna lati bani lorukọ jẹ ni gbogbo rẹ.

Sẹnẹtọ Basiru ni oun ko ni nnkan kan ti oun le fi pamọ, o wa rọ Wike wi pe ko jẹ kawọn pade nile ẹjọ to ba da a loju lori ẹsun to fi kan oun.

Akọwe agba APC tun sọ pe ofuutu fẹẹtẹ ni gbogbo idunkoko Wike tori Wike kii ṣe Ọlọrun.

O ni Wike ko le dunkoko moun tori ninu Ọlọrun nikan ni igbagbọ oun wa.